Amnoni Fipá Bá Tamari Arábìnrin Rẹ̀ Lòpọ̀
Amnoni ṣe bí ẹni pé ara òun kò yá kí ó lè dá wà pẹ̀lú Tamari, arábìnrin rẹ̀ lápá baba, ó fi agbára bá a lò pọ̀, lẹ́yìn náà ó kórìíra rẹ̀, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn lẹ́yìn. Tamari fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ń gbé ní ahoro nínú ilé Absalomu. Inú bí Dafidi gidigidi ṣùgbọ́n kò ṣe nǹkan kan; ọdún méjì lẹ́yìn náà Absalomu mú kí a pa Amnoni níbi àsè ìrẹ́run àgùntàn, ó sì sá lọ.
13 1Lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní arábìnrin arẹwà kan tí a ń pè ní Tamari, Amnoni ọmọ Dafidi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. 2Inú Amnoni bàjẹ́ gidigidi nítorí Tamari arábìnrin rẹ̀, tó fi mú kí ó ṣàìsàn; wúńdíá ni Tamari, Amnoni kò sì rí ọ̀nà kankan láti sún mọ́ ọn. 3Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi; Jonadabu jẹ́ ọlọ́gbọ́n-àrékérekè gidigidi. 4Ó béèrè lọ́wọ́ Amnoni pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń rù bẹ́ẹ̀ ní àràárọ̀, ọmọ ọba? Ṣé o kò ní sọ fún mi?” Amnoni dáhùn pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ Tamari, arábìnrin Absalomu arákùnrin mi.”
5Jonadabu sì wí pé, “Dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, kí o sì dìbọ́n bíi ẹni tí ó ṣàìsàn. Nígbà tí baba rẹ bá wá wò ọ́, sọ fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari arábìnrin mi wá bọ́ mi. Jẹ́ kí ó pèsè oúnjẹ níwájú mi kí n lè máa wò ó, kí n sì lè jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’”
6Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì dìbọ́n bíi ẹni tí ń ṣàìsàn. Nígbà tí ọba wá wò ó, Amnoni wí pé, “Jẹ́ kí Tamari arábìnrin mi wá ṣe àkàrà méjì níwájú mi, kí n lè jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.”
7Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ààfin pé, “Lọ sí ilé Amnoni arákùnrin rẹ, kí o sì ṣe oúnjẹ fún un.” 8Tamari sì lọ sí ilé Amnoni arákùnrin rẹ̀, níbi tí ó gbé dùbúlẹ̀. Ó mú ìyẹ̀fun, ó pò ó, ó ṣe àkàrà níwájú rẹ̀, ó sì dín wọn. 9Ó mú àwokòtò náà, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún un, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ ẹ́. Amnoni wí pé, “Ẹ mú kí gbogbo ènìyàn jáde.” Gbogbo wọn sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 10Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sínú yàrá ìbùsùn, kí n lè jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ti ṣe, ó sì gbé wọn wá fún Amnoni arákùnrin rẹ̀ sínú yàrá ìbùsùn. 11Bí ó ti gbé wọn súnmọ́ ọn kí ó lè jẹ wọ́n, ó dì í mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi sùn, arábìnrin mi.”
12Ó sì dáhùn pé, “Rárá o, arákùnrin mi! Má fipá mú mi. A kì í ṣe irú nǹkan báyìí ní Israẹli. Má ṣe ohun ìtìjú yìí. 13Èmi ńkọ́—níbo ni n ó ti gbé ìtìjú mi lọ? Ìwọ ńkọ́—ìwọ yóò dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ẹ̀gàn ní Israẹli. Jọ̀wọ́, bá ọba sọ̀rọ̀; òun kì yóò fi mí dù ọ́.”
14Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́; níwọ̀n bí ó ti ní agbára ju u lọ, ó fipá mú un, ó sì bá a lòpọ̀. 15Nígbà náà ni Amnoni kórìíra rẹ̀ pẹ̀lú ìkórìíra gidigidi—tí ó pọ̀ ju ìfẹ́ tí ó ti ní sí i lọ. Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì jáde!”
16Ó sì dáhùn pé, “Rárá, lílé mi jáde yìí jẹ́ àṣìṣe tí ó burú ju ohun tí o ti ṣe sí mi lọ.” Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́.
17Ó sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Lé obìnrin yìí jáde kúrò níhìn-ín, kí o sì tì ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lẹ́yìn.”
18Ó wọ aṣọ ìgúnwà gígùn tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, èyí ni aṣọ tí àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀ nígbà náà. Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì tì ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lẹ́yìn. 19Tamari sì fi eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ ìgúnwà gígùn tí ó wọ̀ ya. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń lọ, ó ń sọkún kíkankíkan bí ó ti ń lọ. 20Absalomu arákùnrin rẹ̀ sì wí pé, “Ṣé Amnoni arákùnrin rẹ ti bá ọ lòpọ̀ ni? Pa ẹnu rẹ mọ́ nísinsìnyí, arábìnrin mi; arákùnrin rẹ ni. Má ṣe fi èyí sọ́kàn.” Nítorí náà, Tamari ń gbé bí obìnrin tí ó dánìkanwà nínú ilé Absalomu arákùnrin rẹ̀.
21Nígbà tí Dafidi ọba gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, inú bí i gidigidi. 22Absalomu kò sì sọ ohunkóhun fún Amnoni, yálà rere tàbí búburú, nítorí ó kórìíra rẹ̀ fún bíbá Tamari arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ pẹ̀lú ipá.
Absalomu Gbẹ̀san fún Tamari Arábìnrin Rẹ̀
23Lẹ́yìn ọdún méjì gbáko, Absalomu ní àwọn olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori nítòsí Efraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. 24Absalomu sì tọ ọba lọ, ó wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ní àwọn olùrẹ́run. Ǹjẹ́ ọba àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bá mi lọ?”
25Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Rárá, ọmọ mi, kò yẹ kí gbogbo wa lọ, kí a má baà di ẹrù wíwúwo fún ọ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Absalomu rọ̀ ọ́, ó kọ̀ láti lọ, ṣùgbọ́n ó súre fún un.
26Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí Amnoni arákùnrin mi bá wa lọ.” Ọba sì béèrè pé, “Èéṣe tí yóò fi bá ọ lọ?”
27Ṣùgbọ́n Absalomu rọ̀ ọ́ gidigidi, ó sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ. 28Absalomu sì pa àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra dáadáa. Nígbà tí wáìnì bá mú inú Amnoni dùn, tí mo bá sì wí pé, ‘Ẹ lu Amnoni bolẹ̀,’ ẹ pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi fúnra mi kọ́ ni ó pàṣẹ fún yín? Ẹ mú ọkàn le, kí ẹ sì jẹ́ akíkanjú.”
29Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ ọba dìde, olúkúlùkù sì gun ìbáàkì rẹ̀, wọ́n sì sá lọ.
30Nígbà tí wọ́n wà lọ́nà, Dafidi gbọ́ pé, “Absalomu ti pa gbogbo àwọn ọmọ ọba; kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù.”
31Ọba sì dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ sórí ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í, pẹ̀lú aṣọ wọn tí a fàya. 32Ṣùgbọ́n Jonadabu ọmọ Ṣimea, arákùnrin Dafidi, wí pé, “Kí olúwa mi má ṣe rò pé wọ́n pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, àwọn ọmọ ọba. Amnoni nìkan ni ó kú. Absalomu ti pète èyí láti ọjọ́ tí Amnoni fipá bá Tamari arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀. 33Kí olúwa mi ọba má ṣe fi sọ́kàn, kí ó rò pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ló kú. Amnoni nìkan ni ó kú.”
34Nígbà náà, Absalomu ti sá lọ. Ọ̀dọ́mọkùnrin tí ń ṣọ́nà sì gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ́nà ní ẹ̀gbẹ́ òkè lẹ́yìn rẹ̀. 35Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ti dé. Ó rí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti wí.” 36Bí ó ti ń parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n ń sọkún sókè; ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún kíkorò gidigidi.
37Absalomu sì sá, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Talmai ọmọ Amihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ ní ojoojúmọ́. 38Lẹ́yìn tí Absalomu ti sá, tí ó sì lọ sí Geṣuri, ó dúró níbẹ̀ fún ọdún mẹ́ta. 39Ọkàn Dafidi ọba sì ń fẹ́ gidigidi láti lọ bá Absalomu, nítorí tí a ti tù ú nínú lẹ́yìn ikú Amnoni.