Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Bá Jesu Rìn
A dárúkọ àwọn obìnrin tí ń ṣe onígbọ̀wọ́ iṣẹ́ náà. Òwe kan nípa oríṣiríṣi ilẹ̀ ṣàlàyé ìdí tí ọ̀rọ̀ Baba wa kò fi so èso nínú àwọn kan. Ó mú ìjì dákẹ́, ó dá ọkùnrin kan tí a ń pè ní Legioni sílẹ̀, tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó lọ, lẹ́yìn náà ó wo obìnrin kan tí ń ṣe ìsun ẹ̀jẹ̀ sàn, ó sì jí ọmọbìnrin Jairu dìde.
8 1Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó rìn kiri àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń kéde ìhìnrere ìjọba Baba wa. Àwọn méjìlá wà pẹ̀lú rẹ̀, 2àti àwọn obìnrin kan tí a wo sàn kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí búburú àti àìsàn: Maria, tí a ń pè ní Magdalena, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde, 3àti Joanna, aya Kusa, olórí iṣẹ́ Herodu, àti Susanna, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, tí wọ́n fi ohun ìní ara wọn ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn.
4Bí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ti ń péjọ, tí àwọn ènìyàn láti gbogbo ìlú sì ń tọ̀ ọ́ wá, ó fi òwe sọ̀rọ̀ pé:
5“Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti gbin irúgbìn. Bí ó ti ń gbìn, àwọn irúgbìn kan bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì jẹ wọ́n. 6Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí àpáta; nígbà tí ó hù jáde, ó rọ nítorí àìní omi. 7Àwọn mìíràn bọ́ sáàrin àwọn ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún sì bá a dàgbà, wọ́n sì fún un pa. 8Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó hù, ó sì so èso ní ọgọ́rùn-ún ìlọ́po.” Bí ó ti ń sọ èyí, ó ké jáde pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
9Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ni ìtumọ̀ òwe yìí.
10Ó wí pé, “A ti fi fún yín láti mọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ìjọba Baba wa; àwọn yòókù ni a fi òwe ń bá sọ̀rọ̀, kí ó lè jẹ́ pé, ‘bí wọ́n tilẹ̀ ń wò, wọn kì yóò ríran, bí wọ́n tilẹ̀ ń gbọ́, wọn kì yóò yé e.’”
11“Wàyí o, èyí ni òwe náà: Irúgbìn náà ni ọ̀rọ̀ Baba wa. 12Àwọn tí ó wà ní ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́; nígbà náà ni èṣù wá, ó sì gba ọ̀rọ̀ náà kúrò nínú ọkàn wọn, kí wọ́n má bàa gbàgbọ́ kí a sì gbà wọ́n là. 13Àwọn tí ó wà lórí àpáta ni àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì fi ayọ̀ gbà á, ṣùgbọ́n tí wọn kò ní gbòǹgbò; wọ́n gbàgbọ́ fún ìgbà díẹ̀, nígbà náà ni wọ́n ṣubú lẹ́yìn ní àkókò ìdánwò. 14Èyí tí ó bọ́ sáàrin àwọn ẹ̀gún: àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó gbọ́, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àníyàn ayé, ọrọ̀, àti àwọn ìgbádùn ń fún wọn pa, èso wọn kò sì gbó láé. 15Ṣùgbọ́n èyí tí ó wà nínú ilẹ̀ rere: àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn olóòtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n dìímú ṣinṣin, tí wọ́n sì ń so èso nípa sùúrù.”
Ìmọ́lẹ̀ Tí A Kò Lè Fi Pamọ́
16“Kò sí ẹni tí ó tan fìtílà, tí ó fi ìkòkò bò ó, tàbí tí ó gbé e sábẹ́ ibùsùn; dípò bẹ́ẹ̀, ó gbé e lé orí ọ̀pá, kí àwọn tí ń wọlé lè rí ìmọ́lẹ̀ náà. 17Nítorí kò sí ohun tí ó pamọ́ tí a kì yóò fihàn, kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ tí a kì yóò mọ̀ tí a kì yóò sì mú wá sí ìmọ́lẹ̀. 18Nítorí náà, ẹ kíyèsí bí ẹ ti ń gbọ́, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, a ó fún un ní sí i; ẹnikẹ́ni tí kò ní, àní ohun tí ó rò pé òun ní ni a ó gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”
Ìdílé Baba Wa
19Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn. 20A sì sọ fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọ́n ń fẹ́ láti rí ọ.”
21Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn pé, “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Baba wa tí wọ́n sì ń ṣe é.”
Jesu Pàṣẹ Fún Ìjì
22Ní ọjọ́ kan, òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí òdìkejì adágún náà.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ lọ.
23Bí wọ́n ti ń wa ọkọ̀ lọ, ó sùn lọ. Ìjì líle sì jà lé adágún náà; ọkọ̀ náà kún fún omi, ewu sì dojú kọ wọ́n. 24Wọ́n jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa ń ṣègbé!” Ó dìde, ó bá afẹ́fẹ́ àti ríru omi wí; wọ́n dúró, ó sì rọlẹ̀. 25Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìgbàgbọ́ yín dà?” Pẹ̀lú ẹ̀rù àti ìyàlẹ́nu, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ta ha ni èyí? Ó ń pàṣẹ fún àwọn afẹ́fẹ́ àti omi pẹ̀lú, wọ́n sì ń gbọ́rọ̀ sí i.”
Ọkùnrin Tí A Dá Sílẹ̀ Kúrò Lọ́wọ́ Legioni
26Nígbà náà ni wọ́n wa ọkọ̀ lọ sí agbègbè àwọn ará Gerasa, tí ó wà ní òdìkejì Galili. 27Bí Jesu ti gúnlẹ̀ sí ilẹ̀, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń bá gbé láti ìlú náà pàdé rẹ̀. Fún ìgbà pípẹ́, kò wọ aṣọ, kò sì gbé nínú ilé bí kò ṣe láàrin àwọn ibojì. 28Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké jáde, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì fi ohùn rara wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ mi, Jesu, Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró!” 29Nítorí Jesu ti pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò lára ọkùnrin náà, nítorí ó máa ń dì í mú lọ́pọ̀ ìgbà; bí a tilẹ̀ ṣọ́ ọ, tí a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, yóò ya wọ́n, ẹ̀mí èṣù náà yóò sì lé e lọ sí aginjù.
30Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó wí pé, “Legioni,” nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù ti wọ inú rẹ̀.
31Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó má ṣe pàṣẹ fún wọn láti lọ sínú ọ̀gbun ìsàlẹ̀.
32Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ òkè níbẹ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ó sì yọ̀ǹda rẹ̀. 33Àwọn ẹ̀mí èṣù náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀; agbo náà sì sáré lọ sísàlẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta wọ inú adágún, wọ́n sì rì sínú omi.
34Àwọn olùṣọ́ ẹran rí i, wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ ní ìlú àti ní ìgberíko. 35Ọ̀pọ̀ ènìyàn jáde lọ láti wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà tí a ti dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, ọkàn rẹ̀ sì bàlẹ̀—ẹ̀rù sì ba wọn. 36Àwọn tí ó sì ti rí i sọ fún wọn bí a ti wo ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ti ń bá gbé sàn. 37Gbogbo àwọn ènìyàn agbègbè Gerasa bẹ̀ ẹ́ kí ó fi wọ́n sílẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ńlá mú wọn. Ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi, ó padà lọ. 38Ọkùnrin náà tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde kúrò lára rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ kí ó bá a lọ, ṣùgbọ́n Jesu rán an padà, ó wí pé,
39“Padà sí ilé rẹ; sọ bí Baba wa ti ṣe ohun ńlá tó fún ọ.” Ó sì lọ, ó ń kéde ká gbogbo ìlú náà bí Jesu ti ṣe ohun ńlá tó fún un.
Ìmúláradá àti Àjíǹde Nípa Ìgbàgbọ́
40Nígbà tí Jesu padà dé, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn náà kí i káàbọ̀, nítorí gbogbo wọn ń dúró dè é. 41Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jairu, olórí sínágọ́gù kan, wá, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ Jesu, ó ń bẹ̀ ẹ́ kí ó wá sí ilé rẹ̀, 42nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, tí ó tó ọmọ ọdún méjìlá, tí ó ń kú lọ. Bí Jesu ti ń lọ, ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ̀gbà yí i ká. 43Obìnrin kan wà tí ó ti ń ṣàn ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá; ó ti ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ sórí àwọn oníṣègùn, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó lè wò ó sàn. 44Ó wá sẹ́hìn rẹ̀, ó fọwọ́ kan etí aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì dúró lójú ẹsẹ̀.
45Jesu wí pé, “Ta ni ó fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru wí pé, “Olùkọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó rọ̀gbà yí ọ ká, tí wọ́n sì ń ti ọ.”
46Ṣùgbọ́n Jesu wí pé, “Ẹnìkan fọwọ́ kàn mí, nítorí mo mọ̀ pé agbára ti jáde lára mi.”
47Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun kò lè fi ara pamọ́, ó wá pẹ̀lú ìwárìrì, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ níwájú gbogbo ènìyàn ìdí tí ó fi fọwọ́ kàn án àti bí ó ti sàn lójú ẹsẹ̀.
48Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá; máa lọ ní àlàáfíà.”
49Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹnìkan láti ilé olórí sínágọ́gù náà wí pé, “Ọmọbìnrin rẹ ti kú; má ṣe yọ Olùkọ́ náà lẹ́nu mọ́.”
50Ṣùgbọ́n Jesu gbọ́, ó sì dá a lóhùn pé, “Má bẹ̀rù; kìkì gbàgbọ́, a ó sì gbà á là.”
51Nígbà tí ó dé ilé náà, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá òun wọlé àfi Peteru, Johannu, Jakọbu, àti baba àti ìyá ọmọ náà.
52Gbogbo wọn ń sọkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó wí pé, “Ẹ má ṣe sọkún, nítorí kò kú, ó kàn sùn ni.”
53Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé ó ti kú.
54Ṣùgbọ́n ó mú un lọ́wọ́, ó sì ké jáde pé, “Ọmọ, dìde.”
55Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà, ó sì dìde lójú ẹsẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé kí wọ́n fún un ní nǹkan láti jẹ. 56Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pàṣẹ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni.