Israẹli Ṣọ̀fọ̀ nítorí Samuẹli
Nabali kẹ́gàn àwọn ọkùnrin Dafidi lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣọ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀, Dafidi sì di idà rẹ̀ mọ́ láti pa gbogbo ọkùnrin inú ilé náà. Abigaili gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jáde pẹ̀lú oúnjẹ, ó sì pẹ̀tù sí i lọ́kàn: Baba wa ń pa á mọ́ kúrò nínú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀ sí orí ìtẹ́. Nabali kú.
25 1Samuẹli sì kú, gbogbo Israẹli sì kójọpọ̀ láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀ ní Rama. Nígbà náà ni Dafidi dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù Parani.
2Ọkùnrin kan wà ní Maoni tí ó ní ohun ìní ní Karmeli. Ó ní ọrọ̀ púpọ̀: àgùntàn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ewúrẹ́ ẹgbẹ̀rún kan. Ó sì ń rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀ ní Karmeli. 3Orúkọ ọkùnrin náà ni Nabali, orúkọ aya rẹ̀ sì ni Abigaili. Ó jẹ́ amòye àti arẹwà, ṣùgbọ́n ọkùnrin náà jẹ́ ẹni líle àti ìkà nínú ìṣe rẹ̀—ó sì jẹ́ ọmọ Kalebu. 4Nígbà tí Dafidi wà ní aginjù, ó gbọ́ pé Nabali ń rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀. 5Dafidi sì rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́wàá, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ sí Karmeli. Ẹ lọ bá Nabali kí ẹ sì kí i ní orúkọ mi. 6Ẹ sì wí fún un pé: ‘Kí o wà pẹ́. Àlàáfíà fún ọ, àlàáfíà fún agbo ilé rẹ, àti àlàáfíà fún gbogbo ohun tí o ní.’ 7Mo gbọ́ pé o ní àwọn tí ń rẹ́ irun àgùntàn. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹ wà pẹ̀lú wa; àwa kò ṣe wọ́n ní aburú kankan, kò sì sí ohun kan tí ó sọnù fún wọn ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi wà ní Karmeli. 8Bi àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ léèrè, wọn yóò sì sọ fún ọ. Nítorí náà jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi rí ojú rere ní ojú rẹ, nítorí ọjọ́ àsè ni àwa dé. Jọ̀wọ́ fi ohunkóhun tí o bá lè fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti fún Dafidi ọmọ rẹ.”
9Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Dafidi sì dé, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Nabali ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì dúró.
10Nabali sì dá àwọn ìránṣẹ́ Dafidi lóhùn pé, “Ta ni Dafidi? Ta ni ọmọ Jese yìí? Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ni ń sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀gá wọn lónìí. 11Èéṣe tí èmi yóò fi mú àkàrà mi, omi mi, àti ẹran tí mo pa fún àwọn tí ń rẹ́ irun àgùntàn mi, kí n sì fi fún àwọn ọkùnrin tí èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá?”
12Nítorí náà àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Dafidi yí padà, nígbà tí wọ́n sì dé, wọ́n ròyìn gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.
13Dafidi sì wí fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín di idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́!” Olúkúlùkù sì di idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, Dafidi pẹ̀lú sì di tirẹ̀ mọ́. Nǹkan bí irínwó ọkùnrin ló gòkè tẹ̀lé Dafidi; igba sì dúró pẹ̀lú ẹrù.
14Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì wí fún Abigaili, aya Nabali pé, “Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù wá láti kí ọ̀gá wa, òun sì fi ẹ̀gàn kọlù wọ́n. 15Àwọn ọkùnrin náà ṣoore púpọ̀ sí wa. Wọn kò ṣe wá ní ibi kankan rí, kò sì sí ohun kan tí a sọnù ní gbogbo ìgbà tí a fi ń rìn kiri àwọn pápá pẹ̀lú wọn. 16Wọ́n jẹ́ odi yí wa ká ní òru àti ní ọ̀sán, ní gbogbo ìgbà tí a fi wà pẹ̀lú wọn láti máa bọ́ àgùntàn. 17Ní báyìí, ẹ mọ̀ kí ẹ sì wo ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe, nítorí tí a ti pinnu ibi sí ọ̀gá wa àti sí gbogbo agbo ilé rẹ̀. Ẹni búburú ni í tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò sí ẹni tí ó lè bá a sọ̀rọ̀.”
18Abigaili sì yára mú igba ìṣù àkàrà, ìgò awọ wáìnì méjì, àgùntàn márùn-ún tí a ti pèsè sílẹ̀, nǹkan bí òsùwọ̀n ọkà yíyan márùndínlógójì, ọgọ́rùn-ún ìdì èso àjàrà gbígbẹ, àti igba ìṣù ọ̀pọ̀tọ́, ó sì di wọ́n lé orí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 19Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ síwájú mi; èmi yóò tẹ̀lé e yín.” Ṣùgbọ́n kò sọ ohunkóhun fún Nabali ọkọ rẹ̀. 20Bí ó sì ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ ní ọ̀nà òkè tí ó fara sin, ó pàdé Dafidi àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
21Dafidi sì ti ń wí pé, “Lásán ni mo ṣọ́ gbogbo ohun tí ọkùnrin yìí ní ní aginjù—kò sí ohun kan tí ó sọnù nínú ohun tí ó ní—òun sì fi ibi san oore fún mi. 22Baba wa máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí àwọn ọ̀tá Dafidi, kí ó sì ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí mo bá fi ẹnìkan ọkùnrin sílẹ̀ láàyè nínú gbogbo àwọn tí í ṣe tirẹ̀ títí di àárọ̀.”
23Nígbà tí Abigaili rí Dafidi, ó yára sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó tẹríba délẹ̀. 24Ó sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa mi, ẹ jẹ́ kí ẹ̀bi náà wà lórí èmi nìkan. Jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin yín bá yín sọ̀rọ̀; kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin yín. 25Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ má ṣe náání ọkùnrin búburú yìí, Nabali, nítorí ó dàbí orúkọ rẹ̀—Nabali túmọ̀ sí Òmùgọ̀, ìwà òmùgọ̀ sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. Èmi, ìránṣẹ́bìnrin yín, kò rí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí olúwa mi rán. 26Ní báyìí, olúwa mi, bí Baba wa ti wà láàyè, àti bí ẹ ti wà láàyè: nítorí tí Baba wa ti dá yín dúró kúrò nínú ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àti kúrò nínú gbígbẹ̀san fúnra yín pẹ̀lú ọwọ́ yín, kí àwọn ọ̀tá yín àti gbogbo àwọn tí ń wá ibi sí olúwa mi dàbí Nabali. 27Ní báyìí, jẹ́ kí a fi ẹ̀bùn yìí tí ìránṣẹ́bìnrin yín mú wá fún olúwa mi fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ń tẹ̀lé olúwa mi. 28Ẹ dárí ìrékọjá ìránṣẹ́bìnrin yín jì, nítorí Baba wa yóò fi dandan fi olúwa mi ṣe ìdílé tí yóò dúró pẹ́, nítorí olúwa mi ń jà ogun Baba wa. Kí a má sì rí aburú kankan nínú yín ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. 29Bí ẹnikẹ́ni bá dìde láti lé yín kiri àti láti wá ẹ̀mí yín, a ó dì ẹ̀mí olúwa mi pọ̀ ní àìléwu nínú ìdìpọ̀ àwọn alààyè pẹ̀lú Baba yín; ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwọn ọ̀tá yín ni yóò fi ṣòṣò dànù, bí òkúta tí a ń ta láti inú kànnàkànnà. 30Nígbà tí Baba wa bá ti ṣe fún olúwa mi gbogbo rere tí ó ṣèlérí nípa yín, tí ó sì fi yín ṣe olórí lórí Israẹli, 31olúwa mi kì yóò ní ìbànújẹ́ tàbí ẹ̀bi ọkàn nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ láìnídìí tàbí nítorí gbígbẹ̀san fúnra rẹ̀. Nígbà tí Baba wa bá sì ṣoore sí olúwa mi, ẹ rántí ìránṣẹ́bìnrin yín.”
32Dafidi sì wí fún Abigaili pé, “Ìbùkún ni fún Baba wa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó rán ọ lónìí láti pàdé mi. 33Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rere rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ, ẹni tí ó dá mi dúró lónìí kúrò nínú ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àti kúrò nínú gbígbẹ̀san fúnra mi pẹ̀lú ọwọ́ mi. 34Bí Baba wa, Ọlọ́run Israẹli, ti wà láàyè, ẹni tí ó dá mi dúró láti ṣe ọ́ níbi—bí ìwọ kò bá yára wá pàdé mi, kò sí ẹnìkan ọkùnrin tí í ṣe ti Nabali tí ì bá yè títí di àárọ̀.”
35Dafidi sì gba ohun tí ó mú wá lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Lọ ilé ní àlàáfíà. Wò ó, mo ti gbọ́ ohùn rẹ, mo sì ti gba ìbéèrè rẹ.”
36Nígbà tí Abigaili dé ọ̀dọ̀ Nabali, ó ń ṣe àsè nínú ilé rẹ̀, àsè tí ó yẹ ọba. Ọkàn rẹ̀ sì dùn, ó sì mutí yó gidigidi, nítorí náà kò sọ ohunkóhun fún un títí di àárọ̀. 37Ní àárọ̀, nígbà tí wáìnì fi Nabali sílẹ̀, aya rẹ̀ sì sọ ohun gbogbo fún un. Ọkàn rẹ̀ sì kú nínú rẹ̀, ó sì dàbí òkúta. 38Lẹ́yìn nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá, Baba wa sì lu Nabali, ó sì kú.
39Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Nabali ti kú, ó wí pé, “Ìbùkún ni fún Baba wa, ẹni tí ó ṣe ẹjọ́ mi nítorí ẹ̀gàn tí mo jẹ lọ́wọ́ Nabali, tí ó sì pa ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi. Baba wa ti dá ibi Nabali padà sí orí ara rẹ̀.” Nígbà náà ni Dafidi ránṣẹ́ láti béèrè Abigaili kí ó di aya rẹ̀.
40Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì tọ Abigaili wá ní Karmeli, wọ́n sì wí fún un pé, “Dafidi rán wa láti mú ọ gẹ́gẹ́ bí aya rẹ̀.”
41Ó sì dìde, ó dojúbolẹ̀ délẹ̀, ó sì wí pé, “Èyí ni ìránṣẹ́bìnrin yín, tí ó ṣetán láti sìn àti láti wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.” 42Abigaili sì yára múra, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, òun àti àwọn ọmọbìnrin olùtọ́jú rẹ̀ márùn-ún, ó tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, ó sì di aya rẹ̀. 43Dafidi sì tún ti fẹ́ Ahinoamu ti Jesreeli, bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jẹ́ aya rẹ̀. 44Saulu sì ti fi Mikali ọmọbìnrin rẹ̀, aya Dafidi, fún Paltieli ọmọ Laiṣi, ti Galimu.