Mose àti Aaroni Níwájú Farao
Mose àti Aaroni béèrè lọ́wọ́ Farao fún àjọ̀dún ní aginjù, ó sì sọ fún wọn pé òun kò mọ Ọlọ́run yìí. A dá koríko dúró ṣùgbọ́n iye bíríkì kò yí padà, a na àwọn alábòójútó, Israeli sì dá Mose lẹ́bi. Mose yíjú padà, ó sì béèrè lọ́wọ́ Baba wa ìdí tí ó fi rán òun rárá.
5 1Lẹ́yìn náà, Mose àti Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Baba wa ti Israẹli wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi lọ láti ṣe àjọ̀dún fún mi ní aginjù.”
2Farao dáhùn pé, “Ta ni Ọlọ́run, tí èmi ó fi gbọ́ ohùn rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí Israẹli lọ? Èmi kò mọ Ọlọ́run, èmi kì yóò sì jẹ́ kí Israẹli lọ.”
3Wọ́n sì wí pé, “Baba wa ti pàdé wa. Jẹ́ kí a rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú aginjù láti rú ẹbọ sí Baba wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ó lè fi àjàkálẹ̀-àrùn tàbí idà kọlù wá.”
4Ṣùgbọ́n ọba Ejibiti wí fún wọn pé, “Mose àti Aaroni, èé ṣe tí ẹ̀yin fi ń fa àwọn ènìyàn kúrò nínú iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sí iṣẹ́ àṣekára yín!” 5Farao sì wí pé, “Ẹ wò ó, àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ti pọ̀ nísinsìnyí, ẹ̀yin sì fẹ́ kí wọ́n dẹ́kun iṣẹ́ ṣíṣe!”
6Ní ọjọ́ náà gan-an ni Farao pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn olórí iṣẹ́ tí ń ṣàkóso àwọn ènìyàn pé: 7“Ẹ dẹ́kun fífún àwọn ènìyàn ní koríko láti fi mọ bíríkì bí ti ìgbà àtẹ̀yìnwá. Kí wọ́n fúnra wọn lọ kó koríko jọ.
8Ẹ béèrè iye bíríkì kan náà bí ti àtẹ̀yìnwá; ẹ má ṣe dín in kù. Ọ̀lẹ ni wọ́n; ìdí nìyí tí wọ́n fi ń kígbe pé, ‘Jẹ́ kí a lọ rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’ 9Ẹ mú iṣẹ́ náà le koko fún àwọn ọkùnrin náà, kí wọ́n lè máa ṣe é, kí wọ́n sì kọ etí ikún sí irọ́.”
10Àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn olórí iṣẹ́ jáde lọ, wọ́n sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Báyìí ni Farao wí: ‘Èmi kì yóò fún yín ní koríko mọ́.’ 11Ẹ lọ wá koríko ti ara yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí i—ṣùgbọ́n a kì yóò dín iṣẹ́ yín kù rárá.’” 12Nítorí náà àwọn ènìyàn fọ́nká ká gbogbo ilẹ̀ Ejibiti láti kó àgékù koríko jọ dípò koríko. 13Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń rọ̀ wọ́n pé, “Ẹ parí iye iṣẹ́ ojoojúmọ́ yín, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ẹ ní koríko.” 14Wọ́n lu àwọn olórí iṣẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao ti fi ṣàkóso wọn, wọ́n sì béèrè pé, “Èé ṣe tí ẹ kò fi pé iye bíríkì yín lánàá àti lónìí, bí ti àtẹ̀yìnwá?”
15Nígbà náà ni àwọn olórí iṣẹ́ àwọn ọmọ Israẹli wá, wọ́n sì kígbe sí Farao pé, “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe àwọn ìránṣẹ́ yín báyìí? 16A kò fún àwọn ìránṣẹ́ yín ní koríko kankan, síbẹ̀ wọ́n ń wí fún wa pé, ‘Ẹ mọ bíríkì!’ Ẹ wò ó, a ń lu àwọn ìránṣẹ́ yín, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà jẹ́ ti àwọn ènìyàn yín fúnra wọn.”
17Farao sì wí pé, “Ọ̀lẹ! Ọ̀lẹ ni yín! Ìdí nìyí tí ẹ̀yin fi ń wí pé, ‘Jẹ́ kí a lọ rú ẹbọ sí Ọlọ́run.’ 18Nísinsìnyí, ẹ lọ ṣiṣẹ́. A kì yóò fún yín ní koríko, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ mú iye bíríkì yín kíkún wá.”
19Àwọn olórí iṣẹ́ àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn wà nínú ìdààmú nígbà tí a wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dín iye bíríkì ojoojúmọ́ yín kù.” 20Nígbà tí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ Farao, wọ́n bá Mose àti Aaroni tí wọ́n dúró láti pàdé wọn, 21wọ́n sì wí fún wọn pé, “Kí Baba wa wò yín kí ó sì ṣèdájọ́, nítorí ẹ ti sọ wá di òórùn búburú lójú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ẹ sì ti fi idà lé wọn lọ́wọ́ láti pa wá.”
22Nígbà náà ni Mose padà sọ́dọ̀ Baba wa, ó sì wí pé, “Baba mi Olódùmarè, èé ṣe tí ìwọ fi mú ìdààmú wá sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Èé ṣe tí ìwọ fi rán mi rárá?
23Láti ìgbà tí mo ti lọ sọ́dọ̀ Farao láti sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ, ó ti pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lára, ìwọ kò sì gba àwọn ènìyàn rẹ là rárá.”