Nípa Ohun Ìkọ̀sẹ̀ àti Ìdáríjì
Dáríjì ní ìgbà méje lóòjọ́. Ìgbàgbọ́ tí ó tó irúgbìn kan ti tó. Àwọn ìránṣẹ́ tí ó ṣe ojúṣe wọn kò gba ògo kankan. A wo ọkùnrin mẹ́wàá tí ó ní ẹ̀tẹ̀ sàn, ọ̀kan nínú wọn, ará Samaria, sì padà wá ń yin Baba wa. Ìjọba náà kì í ṣe ibì kan tí a lè nà ọwọ́ sí; ó ti wà láàrin wọn tẹ́lẹ̀.
17 1Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé, “Dájúdájú ohun ìkọ̀sẹ̀ yóò dé, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé! 2Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọrùn rẹ̀, kí a sì jù ú sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀.
3“Ẹ kíyè sí ara yín. Bí arákùnrin rẹ bá dẹ́ṣẹ̀, bá a wí, bí ó bá sì ronú pìwàdà, dárí jì í. 4Bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́, tí ó sì padà sọ́dọ̀ rẹ ní ìgbà méje wí pé, ‘Mo ronú pìwàdà,’ dárí jì í.”
5Àwọn Aposteli sọ fún Olúwa pé, “Fi kún ìgbàgbọ́ wa!”
6Olúwa dáhùn pé, “Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ bí irúgbìn músítádì, ẹ ìbá sọ fún igi mọ́lìbérì yìí pé, ‘Fà tu, kí o sì gbé ara rẹ gbìn sínú Òkun,’ òun ìbá sì gbọ́ tiyín. 7Ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ kan tí ń tu ilẹ̀ tàbí tí ń bọ́ àgùntàn, tí yóò sọ fún un nígbà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Wá kánkán, kí o jókòó sí tábìlì’? 8Ṣé kì yóò kúkú sọ fún un pé, ‘Pèsè oúnjẹ alẹ́ mi sílẹ̀, kí o sì wọ aṣọ láti sìn mí nígbà tí mo bá ń jẹun tí mo sì ń mu, lẹ́yìn náà ìwọ náà lè jẹ, kí o sì mu’?
9“Ǹjẹ́ yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà nítorí ó ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un? 10Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin náà, nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a pa láṣẹ fún yín, ẹ wí pé: ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ tí kò yẹ ni àwa; ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ wa nìkan ni àwa ṣe.’”
Baba Wo Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn
11Nígbà tí ó ń lọ sí Jerusalẹmu, ó ń kọjá láàrin Samaria àti Galili. 12Bí ó ti wọ abúlé kan, àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n ní ẹ̀tẹ̀ pàdé rẹ̀. Wọ́n dúró ní òkèèrè,
13wọ́n sì kígbe sókè pé, “Jesu, Ọ̀gá, ṣàánú wa!”
14Nígbà tí ó rí wọn, ó wí pé, “Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.” Bí wọ́n ti ń lọ, a sì wẹ̀ wọ́n mọ́.
15Ọ̀kan nínú wọn, nígbà tí ó rí i pé a mú òun láradá, ó padà, ó ń fi ohùn rara yin Baba wa, 16ó sì dojúbolẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria sì ni òun.
17Jesu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ a kò ha wẹ̀ mẹ́wàá mọ́? Níbo ni àwọn mẹ́sàn-án yòókù wà? 18Ǹjẹ́ kò sí ẹni tí a rí tí yóò padà wá fi ògo fún Baba wa bí kò ṣe àjèjì yìí?” 19Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.”
Ìjọba Náà Ti Wà Láàrin Yín
20Nígbà tí àwọn Farisi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ìgbà wo ni ìjọba Baba wa yóò dé, ó dáhùn wọn pé, “Ìjọba Baba wa kì í dé pẹ̀lú àkíyèsí tí ojú lè rí, 21bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, ‘Wò ó, níhìn-ín!’ tàbí ‘Níbẹ̀!’ Nítorí ìjọba Baba wa ń bẹ láàrin yín.”
22Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn náà pé, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí ẹ ó fẹ́ gidigidi láti rí ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí i. 23Wọn yóò sì sọ fún yín pé, ‘Wò ó, níbẹ̀!’ tàbí ‘Wò ó, níhìn-ín!’ Ẹ má ṣe lọ, ẹ má sì ṣe lépa wọn. 24Nítorí bí mànàmáná ti ń kọ̀ tí ó sì ń tan ìmọ́lẹ̀ láti igun ọ̀run kan dé èkejì, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ Ènìyàn yóò rí ní ọjọ́ rẹ̀. 25Ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́ ó ní láti jìyà ohun púpọ̀, kí àwọn ìran yìí sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 26Bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ Ọmọ Ènìyàn. 27Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, a sì ń fi wọ́n fúnni ní ìyàwó, títí di ọjọ́ tí Noa wọ inú ọkọ̀, tí ìkún-omi sì dé tí ó pa gbogbo wọn run. 28Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó rí ní ọjọ́ Lọti: wọ́n ń jẹun, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé, 29ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí Lọti kúrò ní Sodomu, iná àti imí-ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run wá, tí ó sì pa gbogbo wọn run, 30bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ tí a ó fi Ọmọ Ènìyàn hàn. 31Ní ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wà lórí òrùlé tí ẹrù rẹ̀ sì wà nínú ilé kò gbọdọ̀ sọ̀kalẹ̀ wá kó o; bákan náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ padà sẹ́yìn. 32Ẹ rántí aya Lọti. 33Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù yóò pa á mọ́. 34Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí ibùsùn kan: a ó gba ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 35Obìnrin méjì yóò máa lọ nǹkan papọ̀; a ó gba ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.” a a v35 Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ jùlọ kò ní ẹsẹ̀ 36 níhìn-ín; àwọn àdàkọ tí ó tẹ̀lé e fi kún un pé: “Ọkùnrin méjì yóò wà lóko; a ó gba ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”
37Wọ́n béèrè pé, “Níbo, Olúwa?” Ó dáhùn pé, “Níbikíbi tí òkú bá wà, níbẹ̀ ni àwọn igún yóò péjọ sí.”