Ẹ Jẹ́ Kí A Lọ sí Ilé Rẹ̀
Orin ìgòkè. Ti Dafidi.
Ayọ̀ arìnrìn-àjò mímọ́ tí ó dé ilé Baba wa, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ dúró gan-an nínú ẹnubodè. Ìlú náà ni ibi tí àwọn ẹ̀yà ń péjọ sí, tí a sì ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo, nítorí náà ó gbàdúrà fún àlàáfíà rẹ̀, ó sì sọ pé nítorí àwọn arákùnrin òun ni òun fi ń ṣe é, kì í ṣe nítorí ara òun.
122 1Inú mi dùn pẹ̀lú àwọn tí ó wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ilé Baba wa.” 2Ẹsẹ̀ wa dúró nínú ibodè rẹ, Jerusalemu. 3Jerusalemu, tí a kọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú tí ó ṣọ̀kan ṣinṣin, 4ibi tí àwọn ẹ̀yà ń gòkè lọ, àwọn ẹ̀yà Baba wa, gẹ́gẹ́ bí òfin fún Israẹli, láti fi ọpẹ́ fún orúkọ Baba wa. 5Nítorí níbẹ̀ ni a ti gbé àwọn ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
6Ẹ gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalemu: “Kí àwọn tí ó fẹ́ ọ wà ní ìsinmi. 7Kí àlàáfíà wà nínú odi rẹ, kí ààbò wà nínú àwọn ilé olódi rẹ.” 8Nítorí àwọn arákùnrin mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi, èmi yóò wí pé, “Kí àlàáfíà wà nínú rẹ.” 9Nítorí ilé Baba wa, èmi yóò wá rere rẹ.