Ọjọ́ Mi Kò Ju Èémí Lọ
Jobu fi ayé rẹ̀ wé iṣẹ́ ẹrú àti ìdúró alágbàṣe fún owó iṣẹ́ rẹ̀: òru yíyí síhìn-ín sọ́hùn-ún, awọ ara tí ń bẹ́. Kò ní dákẹ́. Ó yí orin Sáàmù náà padà di kíkorò, ó béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi ń ṣọ́ ènìyàn tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wo ibòmíràn.
7 1“Ǹjẹ́ ènìyàn kò ha ní iṣẹ́ àṣekára lórí ilẹ̀ ayé, ọjọ́ wọn kò ha sì dàbí ọjọ́ alágbàṣe bí? 2Bí ẹrú tí ó ń ṣàfẹ́rí ibòji, àti bí alágbàṣe tí ó ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀, 3bẹ́ẹ̀ ni a fi oṣù òfo fún mi ní ìpín, a sì yan òru ìpọ́njú fún mi. 4Nígbà tí mo bá dùbúlẹ̀, mo máa ń wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi yóò dìde?’ Ṣùgbọ́n òru náà a sì máa fà gùn, mo sì ń yí síhìn-ín yí sọ́hùn-ún títí di àfẹ̀mọ́júmọ́. 5Ara mi wọ aṣọ kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀; awọ mi le, ó sì tún ya sílẹ̀ padà. 6Ọjọ́ mi yára ju ọkọ̀ ahunṣọ lọ, wọ́n sì dé òpin wọn láìsí ìrètí. 7Ẹ rántí pé èémí lásán ni ẹ̀mí mi; èmi kì yóò tún rí ohun rere kankan mọ́ láéláé. 8Ojú tí ó ń rí mi nísinsin yìí kì yóò rí mi mọ́; ojú yín yóò wà lára mi, èmi kì yóò sì sí mọ́. 9Bí ìkùùkuu ti ń fọ́n ká tí ó sì ń parẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú kì í padà wá sókè; 10kì yóò padà sí ilé rẹ̀ mọ́, ibùgbé rẹ̀ kì yóò sì mọ̀ ọ́n mọ́.
11“Nítorí náà, èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́; èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìrora ẹ̀mí mi, èmi yóò ṣàròyé nínú ìkorò ọkàn mi. 12Èmi ha jẹ́ Òkun, tàbí ẹranko ńlá inú Òkun, tí ẹ fi yan olùṣọ́ lórí mi? 13Nígbà tí mo bá wí pé, ‘Ibùsùn mi yóò tù mí nínú, àkéte mi yóò mú ẹ̀dùn ọkàn mi fúyẹ́,’ 14nígbà náà ni ẹ ń fi àlá dẹ́rù ba mí, ẹ sì ń fi ìran páyà mí, 15tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi yàn ìfúnpa àti ikú dípò ara mi yìí. 16Mo ń ṣòfò lọ; èmi kì yóò wà láàyè títí láé. Ẹ fi mí sílẹ̀ nìkan, nítorí èémí lásán ni ọjọ́ mi.
17“Kí ni ènìyàn, tí ẹ fi gbé e ga tó bẹ́ẹ̀, tí ẹ sì fi ọkàn yín lé e lórí, 18tí ẹ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò ní àràárọ̀, tí ẹ sì ń dán an wò ní àkókò gbogbo? 19Yóò ti pẹ́ tó kí ẹ tó yí ojú yín padà kúrò lọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì fi mí sílẹ̀ fún ìgbà tó tó bẹ́ẹ̀ kí n lè gbé itọ́ mi mì? 20Bí mo bá ti dẹ́ṣẹ̀, kí ni mo ha ṣe yín, ẹ̀yin olùṣọ́ aráyé? Èéṣe tí ẹ fi fi mí ṣe ohun ìtafà yín, tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi di ẹrù wíwúwo fún ara mi? 21Èéṣe tí ẹ kò fi ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì, tí ẹ kò sì fi ní mú ẹ̀bi mi kúrò? Nítorí láìpẹ́ èmi yóò dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀; ẹ ó wá mi kiri, ṣùgbọ́n èmi kì yóò sí mọ́.”