Ìbúra Jobu nípa Ọkàn Mímọ́
Jobu parí pẹ̀lú ìbúra, ó ṣí ayé rẹ̀ sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan: kò sí ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́, kò sí irọ́, kò sí kíkọ ẹ̀tọ́ fún ìránṣẹ́, kò sí jíjẹun nìkan nígbà tí ọmọ òrukàn ń pa ebi, kò sí gbígbẹ́kẹ̀lé wúrà. Ó fọwọ́ sí i, ó sì béèrè ìwé ẹ̀sùn. Lẹ́yìn náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kàn dópin.
31 1“Mo bá ojú mi dá májẹ̀mú; báwo wá ni mo ṣe lè tẹjúmọ́ wúńdíá wò? 2Nítorí ìpín wo ni èmi yóò ní láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run òkè, ogún wo láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè tí ó ń bẹ lókè ọ̀run? 3Kì í ha ṣe ìparun fún aláìṣòdodo, àti ìjàǹbá fún àwọn tí ń ṣe ibi? 4Kò ha rí ọ̀nà mi, tí kò sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?
5“Bí mo bá ti fi èké gbé ayé, tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn, 6jẹ́ kí ó fi òsùwọ̀n òdodo wọ̀n mí, kí Ọlọ́run sì mọ ìwà ìdúró ṣinṣin mi, 7bí ìṣísẹ̀ mi bá ti yà kúrò ní ọ̀nà, tí ọkàn mi sì tẹ̀lé ojú mi, tí àbàwọ́n kankan bá sì lẹ̀ mọ́ ọwọ́ mi, 8nígbà náà jẹ́ kí n gbìn kí ẹlòmíràn sì jẹ ẹ́, kí a sì fa ohun tí ó hù jáde fún mi tu.
9“Bí obìnrin bá ti tan ọkàn mi, tí mo sì ba lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi, 10nígbà náà jẹ́ kí aya mi máa sìn ọkùnrin mìíràn, kí àwọn ẹlòmíràn sì bá a sùn. 11Nítorí ìyẹn ìbá jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ ìtìjú, ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ìdájọ́; 12nítorí iná ni tí ń jó dé ibi Ìparun, tí yóò sì jó gbogbo ìkórè mi run.
13“Bí mo bá ti sẹ́ ẹ̀tọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin tàbí obìnrin nígbà tí wọ́n mú ẹ̀dùn ọkàn wọn wá sọ́dọ̀ mi, 14kí ni èmi yóò wá ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá béèrè ìṣírò lọ́wọ́ mi, kí ni èmi yóò dá a lóhùn? 15Ẹni tí ó dá mi nínú ìyá, kì í ha ṣe òun náà ló dá ọmọ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú? Kì í ha ṣe ẹni kan náà ló mọ àwa méjèèjì nínú ìyá?
16“Bí mo bá ti dá tálákà lẹ́kun ohun tí wọ́n nílò, tàbí tí mo jẹ́ kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì, 17tàbí tí mo jẹ oúnjẹ mi nìkan nígbà tí aláìníbaba kò rí jẹ, 18bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi, mo tọ́ ọ bí baba ti ń ṣe, àti pé láti inú ìyá mi, mo ṣe amọ̀nà fún opó, 19bí mo bá ti rí ẹnì kan tí ó ń ṣègbé nítorí àìní aṣọ, tàbí aláìní tí kò ní ìbora, 20bí gbogbo ara rẹ̀ kò bá súre fún mi nítorí mo fi irun àgùntàn mi mú un gbóná, 21bí mo bá ti gbé ọwọ́ mi sókè lòdì sí aláìníbaba nítorí mo rí àtìlẹ́yìn mi ní ẹnu ibodè, 22nígbà náà jẹ́ kí èjìká mi bọ́ kúrò ní ihò rẹ̀, kí apá mi sì ṣẹ́ ní oríkè rẹ̀. 23Nítorí ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀rù fún mi, àti pé níwájú ọláńlá rẹ̀ èmi kò lè ṣe ohunkóhun.
24“Bí mo bá ti fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo wí fún wúrà dáradára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’ 25bí mo bá ti yọ̀ pé ọrọ̀ mi pọ̀, àti pé ọwọ́ mi ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀, 26bí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń rìn nínú ọlá, 27tó bẹ́ẹ̀ tí a fi tan ọkàn mi ní ìkọ̀kọ̀, tí ọwọ́ mi sì fi ẹnu kò wọ́n ní ìjọsìn, 28èyí náà ìbá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ìdájọ́, nítorí èmi ìbá ti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run òkè.
29“Bí mo bá ti yọ̀ sí ìparun ẹni tí ó kórìíra mi, tàbí tí inú mi dùn nígbà tí ìyọnu bá a. 30Èmi kò jẹ́ kí ẹnu mi ṣẹ̀ nípa pípe ègún sílẹ̀ lórí ẹ̀mí rẹ̀, 31bí àwọn ọkùnrin inú agboolé mi kò bá tí ì wí rí pé, ‘Ta ni kò yó láti orí tábìlì rẹ̀?’, 32kò sí àlejò tí ó sùn ní òde ní alẹ́ rí, nítorí mo ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún arìnrìn àjò. 33Bí mo bá ti bo ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí àwọn ẹlòmíràn ti ń ṣe, tí mo sì fi ẹ̀bi mi pamọ́ sínú ọkàn mi, 34nítorí mo bẹ̀rù ìjọ ènìyàn gidigidi, tí ẹ̀gàn àwọn ìdílé sì dẹ́rù ba mí, tó fi jẹ́ pé mo dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí n kò sì jáde sóde.
35“Háà, ìbá ṣe pé ẹnìkan yóò gbọ́ ti mi! Èyí ni àmì ọwọ́ mi—jẹ́ kí Olódùmarè dá mi lóhùn! Jẹ́ kí olùfisùn mi kọ ẹ̀sùn rẹ̀ sílẹ̀! 36Dájúdájú èmi ìbá gbé e ka èjìká mi, èmi ìbá sì dì í mọ́ mi bí adé. 37Èmi ìbá ṣírò gbogbo ìṣísẹ̀ mi fún un; bí ọmọ-ọba ni èmi ìbá fi súnmọ́ ọn.
38“Bí ilẹ̀ mi bá ti ké pè lòdì sí mi, tí isà oko rẹ̀ sì sọkún papọ̀, 39bí mo bá ti jẹ èso rẹ̀ láìsan owó, tàbí tí mo fún ẹ̀mí àwọn onílẹ̀ rẹ̀ pa, 40nígbà náà jẹ́ kí ẹ̀gún hù dípò ọkà jéró, àti èpò búburú dípò ọkà bálì.” Ọ̀rọ̀ Jobu parí nìyí.