Egungun Tí A Mú Jáde Kúrò Nínú Ibojì
Ènìyàn a máa ṣubú, a sì tún dìde; àwọn ènìyàn yìí ṣubú, wọ́n sì wà nílẹ̀. Àwọn ẹyẹ tí ń ṣí kiri mọ àkókò wọn ju bí Juda ti mọ ọ̀nà Baba rẹ̀ lọ. Jeremáyà, tí ìbànújẹ́ ti mú ṣàìsàn, béèrè bóyá kò sí ìkunra ní Gileadi — orí náà kò sì dá a lóhùn.
8 1“Ní àkókò náà,’ ni Baba wa wí, ‘wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì, àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu jáde kúrò nínú ibojì wọn. 2A óò tẹ́ wọn síta síwájú oòrùn, òṣùpá, àti gbogbo ogun ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́, tí wọ́n sìn, tí wọ́n tẹ̀lé, tí wọ́n ṣèwádìí lọ́dọ̀, tí wọ́n sì foríbalẹ̀ fún—tí a kì yóò kó jọ, tí a kì yóò sìnkú, wọn yóò sì dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀. 3Gbogbo àwọn ìyókù ti ìdílé burúkú yìí, níbikíbi tí mo ti lé wọn lọ, wọn yóò yan ikú dípò ìyè,’ ni Baba àwọn ọmọ ogun ọ̀run wí.”
Àwọn Ènìyàn Tí Kì Yóò Padà
4“Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Baba wa wí: Bí àwọn ènìyàn bá ṣubú, wọn kì í ha padà dìde bí? Bí ẹnìkan bá yà kúrò, kì í ha padà bọ̀ bí? 5Èéṣe tí àwọn ènìyàn yìí, Jerusalẹmu, fi yà kúrò nínú ìpẹ̀yìndà àìnípẹ̀kun? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti padà bọ̀.’ 6Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹni tí ó yà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀, tí ó ń béèrè pé, ‘Kí ni mo ṣe?’ Olúkúlùkù ń sáré ipa ọ̀nà tirẹ̀, bí ẹṣin tí ń sáré wọ inú ogun. 7Kódà àkọ̀ ní ojú ọ̀run mọ àwọn àkókò tí a yàn fún un, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀, àti ẹ̀gà sì ń kíyèsí àkókò ìpadàbọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ àwọn ọ̀nà òdodo ti Baba wọn. 8Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé, ‘Àwa gbọ́n, àti òfin Baba wa wà pẹ̀lú wa,’ nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù irọ́ ti àwọn akọ̀wé ti sọ ọ́ di irọ́? 9A óò dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n; ẹ̀rù yóò bà wọ́n, a óò sì dẹkùn mú wọn. Kíyèsi, wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀, ọgbọ́n kín ni ó sì kù sí wọn lọ́wọ́? 10Nítorí náà, èmi yóò fi àwọn aya wọn fún àwọn ẹlòmíràn, àti àwọn oko wọn fún àwọn olówó tuntun. Nítorí láti orí ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, gbogbo wọn ni ojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó; láti orí wòlíì títí dé àlùfáà, gbogbo wọn ni ó ń hùwà ẹ̀tàn.’ 11Wọ́n ń wo ọgbẹ́ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò jámọ́ nǹkankan, wí pé, ‘Àlàáfíà, àlàáfíà,’ nígbà tí kò sí àlàáfíà. 12Ojú ha tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe bí? Rárá, ojú kò tì wọ́n rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ bí a ṣe ń tì lójú. Nítorí náà, wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tí ó ti ṣubú; nígbà tí mo bá bá wọn wí, a óò rẹ̀ wọn sílẹ̀,’ ni Baba wa wí.” 13‘Èmi yóò kó wọn jọ pátápátá,’ ni Baba wa wí. ‘Kì yóò sí èso àjàrà lórí àjàrà, kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ọ̀pọ̀tọ́, ewé yóò sì rọ; ohun tí mo fi fún wọn yóò kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn.’
14“Èéṣe tí àwa fi jókòó síbí? Ẹ jọ pọ̀! Ẹ jẹ́ kí a sá lọ sí àwọn ìlú olódi, kí a sì ṣègbé níbẹ̀, nítorí Baba wa ti pinnu pé kí a ṣègbé, ó sì ti fún wa ní omi oró láti mu, nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí i.”
15A ní ìrètí àlàáfíà, ṣùgbọ́n kò sí ohun rere tí ó dé; a ní ìrètí àkókò ìwòsàn, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ìpayà ló wà. 16Ìfún imú àwọn ẹṣin ọ̀tá ni a ń gbọ́ láti Dani; nípa ìró híhun àwọn akọ ẹṣin wọn, gbogbo ilẹ̀ náà wárìrì. Wọ́n wá, wọ́n sì jẹ ilẹ̀ náà run àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, ìlú náà àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
17“Nítorí kíyèsi, èmi ń rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, àwọn paramọ́lẹ̀ tí a kò lè fi ìpè kó, wọn yóò sì bù yín jẹ,” ni Baba wa wí.
Jeremáyà Sunkún Fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀
18Ayọ̀ mi ti lọ, ìbànújẹ́ bò mí mọ́lẹ̀; ọkàn mi ṣàìsàn nínú mi. 19Gbọ́—igbe ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà réré: “Baba wa kò ha sí ní Síónì bí? Ọba rẹ̀ kò ha sí nínú rẹ̀ mọ́ bí?” “Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú àwọn ère gbígbẹ́ wọn, pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí kò wúlò? 20Ìkórè ti kọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí, a kò sì gbà wá là.” 21Nítorí ọgbẹ́ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi, ọkàn mi fọ́; mo ń ṣọ̀fọ̀, ẹ̀rù sì dì mí mú. 22Kò ha sí ìkunra ìwòsàn ní Gileadi bí? Kò ha sí oníṣègùn níbẹ̀ bí? Èéṣe nígbà náà tí ìwòsàn ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi kò fi dé?