Ọjọ́ Ìgbéyàwó Ọba
Obìnrin náà ń wá ẹni tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ kiri ìlú tí ó ṣókùnkùn, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́, lẹ́yìn náà ó rí i, kò sì jẹ́ kí ó lọ títí ó fi mú un wá sí ilé ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà àwọn ohùn mìíràn ń wo bí kẹ̀kẹ́ Solomoni tí a ń ṣọ́ ti ń bọ̀, ọba tí a dé ládé ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀.
3 1Ní orí ibùsùn mi ní gbogbo òru, mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́; mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i. 2Nísinsìnyí èmi yóò dìde, èmi yóò sì máa rìn kiri ìlú, káàkiri àwọn òpópónà àti àwọn gbàgede; èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i. 3Àwọn olùṣọ́ rí mi bí wọ́n ti ń ṣọ́ ìlú kiri. Mo béèrè pé, “Ṣé ẹ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” 4Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá wọn ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí èmi fi mú un wá sí ilé ìyá mi, sí yàrá ẹni tí ó lóyún mi. 5Mo fi yín bú, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalemu, mo fi àwọn èkùlù àti àwọn abo àgbọ̀nrín inú pápá bú yín: ẹ má ṣe ru ìfẹ́ sókè, ẹ má sì ṣe jí i dìde títí yóò fi wù ú.
6Ta ni èyí tí ó ń gòkè wá láti aginjù bí ọ̀wọ̀n èéfín, tí a fi òjìá àti tùràrí olóòórùn dídùn kùn, pẹ̀lú gbogbo lulú olóòórùn dídùn ti oníṣòwò? 7Wò ó—àkéte ti Solomoni tìkára rẹ̀ nìyí, pẹ̀lú ọgọ́ta alágbára ọkùnrin tí ó yí i ká, nínú àwọn alágbára ọkùnrin Israẹli, 8gbogbo wọn di idà mú, tí a kọ́ fún ogun, olúkúlùkù pẹ̀lú idà rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, láti dojú kọ ẹ̀rù òru. 9Solomoni ọba ṣe àkéte kan fún ara rẹ̀ láti inú igi Lebanoni. 10Ó fi fàdákà ṣe àwọn òpó rẹ̀, ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi aṣọ elése àlùkò ṣe ìjókòó rẹ̀; àwọn ọmọbìnrin Jerusalemu sì fi ìfẹ́ ṣe ọ̀ṣọ́ inú rẹ̀. 11Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni, kí ẹ sì wo Solomoni ọba, tí ó dé adé tí ìyá rẹ̀ fi lé e lórí ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ní ọjọ́ tí ọkàn rẹ̀ yọ̀.