Kìkì Kristi tí A Kàn Mọ́ Àgbélébùú
Paulu mọ̀ọ́mọ̀ wá láìsí ọ̀rọ̀ dídùn tí ń wúni lórí, bí kò ṣe Kristi tí a kàn mọ́ agbélébùú nìkan, kí ìgbàgbọ́ wọn lè dúró lórí agbára Baba wa dípò ọgbọ́n olùsọ̀rọ̀. Ọgbọ́n tí ó ń kọ́ni jẹ́ èyí tí a fi pamọ́, tí a ti pèsè ṣáájú kí ìgbà tó bẹ̀rẹ̀, tí a sì lè mọ̀ kìkì bí Ẹ̀mí Baba wa ti ń fi í hàn.
2 1Nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín, ẹ̀yin ará, èmi kò fi ọ̀rọ̀ ọ̀ṣọ́ tàbí ọgbọ́n kéde ẹ̀rí Baba wa. 2Nítorí mo pinnu láti má mọ ohunkóhun láàrin yín bí kò ṣe Jesu Kristi, àti òun tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 3Mo sì wá sọ́dọ̀ yín ní àìlera, ní ìbẹ̀rù, àti pẹ̀lú ìwárìrì púpọ̀. 4Ọ̀rọ̀ mi àti ìwàásù mi kò gbékarí ọ̀rọ̀ ìyíni-lọ́kàn-padà ti ọgbọ́n, bí kò ṣe lé ìfihàn Ẹ̀mí Mímọ́ àti ti agbára, 5kí ìgbàgbọ́ yín má bàa gbékarí ọgbọ́n ènìyàn bí kò ṣe agbára Baba wa.
6Àwa a máa sọ ọgbọ́n láàrin àwọn tí ó dàgbà ní ẹ̀mí—kì í ṣe ọgbọ́n ayé yìí, tàbí ti àwọn alákòóso ayé yìí, tí ń parẹ́ lọ. 7Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ ọgbọ́n Baba wa, àṣírí tí ó pamọ́ tí Baba wa ti yàn tẹ́lẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀, fún ògo wa. 8Kò sí ẹnìkan nínú àwọn alákòóso ayé yìí tí ó mọ̀ ọ́n; ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọn kì bá tí kan Olúwa ògo mọ́ àgbélébùú. 9Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ohun tí ojú kankan kò tí ì rí, tí etí kankan kò tí ì gbọ́, tí kò sì wọ ọkàn ènìyàn kankan rí—nǹkan wọ̀nyí ni Baba wa ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀.”
10Ṣùgbọ́n Baba wa ti fi wọ́n hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí; nítorí Ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, àní ìjìnlẹ̀ Baba wa. 11Ta ni ó mọ èrò inú ènìyàn bí kò ṣe ẹ̀mí ara rẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni, kò sí ẹni tí ó mọ èrò Baba wa bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba wa. 12Àwa kò gba ẹ̀mí ayé, bí kò ṣe Ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wa wá, kí àwa lè mọ ohun tí Baba wa fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 13Èyí ni àwa ń sọ, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tí ọgbọ́n ènìyàn ń kọ́ni ṣùgbọ́n tí Ẹ̀mí ń kọ́ni, ní ṣíṣàlàyé òtítọ́ tẹ̀mí fún àwọn ènìyàn tẹ̀mí. 14Ẹni tí kò ní Ẹ̀mí kì í gba ohun tí ó ti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Baba wa wá; òmùgọ̀ ni ó jẹ́ lójú rẹ̀, kò sì lè mọ̀ ọ́n, nítorí pé nípasẹ̀ òye tẹ̀mí ni a fi ń fòye mọ̀ ọ́n. 15Ẹni tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí ń fòye mọ ohun gbogbo, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ kò sí lábẹ́ ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. 16Nítorí “ta ni ó ti mọ èrò inú Baba wa, láti kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́?” Ṣùgbọ́n àwa ní èrò inú Kristi.