Àwọn Orílẹ̀-èdè tí A Fi Sílẹ̀ láti Dán Israẹli Wò
A fi àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà láti dán wò bóyá Israẹli yóò gbọ́. Nígbà tí Israẹli gbàgbé Baba wọn, Kuṣani-Riṣataimu jọba lé wọn lórí fún ọdún mẹ́jọ títí a fi gbé Otnieli dìde. Lẹ́yìn náà, Ehudi ọlọ́wọ́ òsì fi idà pamọ́ sí itan ọ̀tún rẹ̀, ó pa Eglon ọba tí ó sanra nínú yàrá òkè rẹ̀, ó sì ti ilẹ̀kùn.
3 1Wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Baba wa fi sílẹ̀ láti fi dán Israẹli wò—gbogbo àwọn tí kò tí ì mọ ogun èyíkéyìí ti Kenaani. 2(Ó ṣe èyí kìkì kí àwọn ìran Israẹli tí kò tí ì mọ ogun rí lè kọ́ ọ.). 3Àwọn orílẹ̀-èdè náà ni: àwọn alákòóso Filistini márùn-ún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni, láti Òkè Baali-Hermoni dé Lebo-Hamati. 4Wọ́n wà láti dán Israẹli wò—bóyá wọn yóò pa àṣẹ Baba wa mọ́, tí a ti ipasẹ̀ Mose fi fún àwọn baba ńlá wọn. 5Nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbé láàrin àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Jebusi. 6Wọ́n fẹ́ àwọn ọmọbìnrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì fi àwọn ọmọbìnrin ara wọn fún àwọn ọmọkùnrin wọn, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.
Baba Gbé Otnieli Dìde
7Israẹli ṣe búburú ní ojú Baba wa, wọ́n gbàgbé Baba wọn, wọ́n sì ń sin àwọn Baali àti àwọn Aṣerah. 8Nítorí náà ìbínú Baba wa ru sí Israẹli; ó sì tà wọ́n fún Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu, ẹni tí Israẹli sìn fún ọdún mẹ́jọ. 9Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ké pe Baba wa, ó gbé olùgbàlà dìde—Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu—ẹni tí ó gbà wọ́n là. 10Ẹ̀mí Baba wa bà lé e, ó sì ṣe ìdájọ́ Israẹli. Ó lọ sí ogun, Baba wa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé e lọ́wọ́, ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu. 11Nígbà náà ilẹ̀ náà sì sinmi fún ogójì ọdún, títí Otnieli ọmọ Kenasi fi kú.
Baba Gbé Ehudi Dìde
12Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe búburú ní ojú Baba wa, àti nítorí wọ́n ṣe búburú yìí, Baba wa sọ Egloni ọba Moabu di alágbára sí Israẹli. 13Egloni kó àwọn ará Ammoni àti àwọn ará Amaleki jọ, ó lọ ó sì kọlu Israẹli, wọ́n sì gba Ìlú Ọ̀pẹ. 14Àwọn ọmọ Israẹli sin Egloni ọba Moabu fún ọdún méjìdínlógún. 15Àwọn ọmọ Israẹli tún ké pe Baba wa; ó gbé Ehudi ọmọ Gera dìde, ọmọ Benjamini tí ó jẹ́ amọ̀wọ́-òsì, gẹ́gẹ́ bí olùgbàlà. Wọ́n sì fi ọwọ́ rẹ̀ rán ọrẹ sí Egloni ọba Moabu. 16Ehudi sì rọ idà olójú méjì fún ara rẹ̀, tí ó tó bíi inṣì méjìdínlógún ní gígùn, ó sì so ó mọ́ abẹ́ aṣọ rẹ̀ ní itan ọ̀tún rẹ̀. 17Ó sì gbé ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, ẹni tí ó jẹ́ ọkùnrin tí ó sanra gidigidi. 18Nígbà tí Ehudi parí gbígbé ọrẹ náà wá, ó rán àwọn ènìyàn tí ó ru u lọ. 19Ó padà sẹ́yìn kúrò ní ibi àwọn ère tí ó wà nítòsí Gilgali, ó wí pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan fún ọ, ọba.” Ọba náà sì wí pé, “Dákẹ́!” gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì fi í sílẹ̀.
20Ehudi sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, bí ó ti jókòó ní òun nìkan ní yàrá òkè rẹ̀ tí ó tutù. Ehudi sì wí pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ọ.” Ọba náà sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀. 21Ehudi sì na ọwọ́ òsì rẹ̀, ó mú idà náà kúrò ní itan ọ̀tún rẹ̀, ó sì gbún un bọ inú Egloni. 22Èèkù rẹ̀ sì wọ inú lẹ́yìn ojú idà; ọ̀rá sì bò ó mọ́lẹ̀. Nítorí tí Ehudi kò fa idà náà jáde kúrò nínú rẹ̀, ìfun rẹ̀ sì tú jáde. 23Ehudi sì jáde lọ sí ìloro, ó ti àwọn ìlẹ̀kùn yàrá òkè náà pa sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì tì wọ́n.
24Lẹ́yìn tí ó lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rí àwọn ìlẹ̀kùn yàrá òkè náà tí a tì, wọ́n sì wí pé, “Ó ṣe tán ló ń yàgbẹ́ nínú yàrá tí ó tutù náà.” 25Wọ́n dúró títí ojú fi tì wọ́n, ṣùgbọ́n kò tí ì ṣí àwọn ìlẹ̀kùn yàrá òkè náà. Nítorí náà wọ́n mú kọ́kọ́rọ́ náà, wọ́n ṣí wọn, wọ́n sì rí olúwa wọn tí ó ṣubú lulẹ̀, tí ó ti kú.
26Nígbà tí wọ́n ń falẹ̀, Ehudi sá àsálà. Ó kọjá àwọn ère náà, ó sì sá àsálà lọ sí Seira. 27Ó dé, ó fọn ìwo àgbò ní àwọn òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì bá a sọ̀kalẹ̀ láti àwọn òkè náà, Ehudi ń ṣáájú wọn. 28Ó wí pé, “Ẹ tẹ̀lé mi, nítorí Baba wa ti fi Moabu àwọn ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e sọ̀kalẹ̀, wọ́n gba àwọn ibùréré Jordani lọ́wọ́ Moabu, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni rékọjá. 29Ní àkókò náà wọ́n pa bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ará Moabu, gbogbo wọn jẹ́ alágbára, ọkùnrin tí ó lera; kò sí ọ̀kan tí ó sá àsálà. 30Nítorí náà a tẹ Moabu lórí ba ní ọjọ́ náà lábẹ́ ọwọ́ Israẹli, ilẹ̀ náà sì sinmi fún ọgọ́rin ọdún.
31Ṣamgari ọmọ Anati sì tẹ̀lé e, ó pa ẹgbẹ̀ta àwọn Filistini pẹ̀lú ẹ̀gún màlúù; òun náà gba Israẹli là pẹ̀lú.