Elifasi Tún Sọ̀rọ̀
Níkẹyìn Elifasi hùmọ̀ ẹ̀sùn: bíbọ́ aṣọ lára òtòṣì, kíkọ omi fún ẹni tí ó rẹ̀, rírán àwọn opó lọ lọ́wọ́ òfo. Ó sọ fún Jobu pé kí ó tẹríba, kí ó tẹ́ wúrà rẹ̀ sínú erùpẹ̀, kí Olódùmarè sì jẹ́ wúrà rẹ̀. Ìmọ̀ràn náà dún dáradára, ṣùgbọ́n ẹ̀sùn náà jẹ́ èké.
22 1Nígbà náà ni Elifasi ará Temani dáhùn pé: 2“Ènìyàn ha lè ṣe àǹfààní kankan fún Ọlọ́run bí? Dájúdájú, ọlọ́gbọ́n ènìyàn ṣe àǹfààní fún ara rẹ̀ nìkan ni. 3Ǹjẹ́ ó jẹ́ adùn kankan fún Olódùmarè bí ìwọ bá jẹ́ olódodo, tàbí èrè kankan fún un bí ìwọ bá ń gbé ní àìlẹ́bi? 4Ǹjẹ́ nítorí ìbẹ̀rù rẹ ni ó fi ń bá ọ wí, tí ó sì ń mú ọ wá sí ìdájọ́? 5Ǹjẹ́ ìwà búburú rẹ kò tóbi bí? Ǹjẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò ní òpin bí? 6Nítorí ìwọ béèrè ohun ìgbọ̀wọ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì bọ́ aṣọ kúrò lára àwọn tí ń wà ní ìhòòhò. 7Ìwọ kò fún àwọn tí ó rẹ̀ ní omi láti mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa. 8Ọkùnrin alágbára ni ó ni ilẹ̀ náà, ẹni tí a ṣe ojúrere sí ni ó sì ń gbé inú rẹ̀. a a v8 Elifasi ń fi hàn pé Jobu kà ilẹ̀ sí ohun tí ó jẹ́ ti alágbára nìkan, tí ó fi àwọn tálákà sílẹ̀ láìní ohunkóhun. 9Ìwọ rán àwọn opó lọ ní ọwọ́ òfo, ìwọ sì tẹ apá àwọn ọmọ òrukàn mọ́lẹ̀. 10Ìdí nìyí tí àwọn okùn-ìdẹkùn fi yí ọ ká, tí ẹ̀rù òjijì sì bò ọ́ mọ́lẹ̀; 11tàbí òkùnkùn, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran, tí àgbàrá omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀. 12Ǹjẹ́ Ọlọ́run kò ha wà ní òkè gíga ọ̀run bí? Wò ó bí àwọn ìràwọ̀ tí ó ga jùlọ ti ga tó! 13Síbẹ̀ ìwọ wí pé, ‘Kí ni Ọlọ́run mọ̀? Ǹjẹ́ ó lè ṣe ìdájọ́ láàrin òkùnkùn biribiri báyìí? 14Àwọsánmà tí ó nípọn bò ó mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi lè ríran, ó sì ń rìn lórí ìforí ọ̀run.’ 15Ǹjẹ́ ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà àtijọ́ tí àwọn ènìyàn búburú ti rìn? 16A gbá wọn lọ kí àkókò wọn tó pé, àgbàrá omi sì gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ. 17Wọ́n wí fún Ọlọ́run pé, ‘Fi wá sílẹ̀! Kí ni Olódùmarè lè ṣe sí wa?’ 18Síbẹ̀ òun ni ó fi ohun rere kún ilé wọn—nítorí náà èmi kò fẹ́ nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ràn àwọn ènìyàn búburú. 19Àwọn olódodo rí i, inú wọn sì dùn; àwọn aláìlẹ́bi fi àwọn ènìyàn búburú ṣe yẹ̀yẹ́, wí pé, 20‘Dájúdájú, a ti pa àwọn ọ̀tá wa run, iná sì ti jó ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn.’ 21Tẹríba fún Ọlọ́run nísinsìnyí, kí o sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀; báyìí ni rere yóò fi wá sọ́dọ̀ rẹ. 22Gba ẹ̀kọ́ láti ẹnu rẹ̀, kí o sì to àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ sínú ọkàn rẹ. 23Bí ìwọ bá padà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a ó mú ọ bọ̀ sípò; bí ìwọ bá lé àìṣòdodo jìnnà réré kúrò ní ilé rẹ, 24tí o sì fi wúrà rẹ lélẹ̀ sínú ekuru, wúrà Ofiri láàrin àwọn òkúta odò, b b v24 Ofiri gbajúmọ̀ ní ayé ìgbàanì gẹ́gẹ́ bí orísun wúrà tí ó dára jùlọ. 25nígbà náà Olódùmarè fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ wúrà rẹ, fàdákà iyebíye rẹ. 26Nígbà náà ni ìwọ yóò ní inú dídùn nínú Olódùmarè, ìwọ yóò sì gbé ojú rẹ sókè sí Ọlọ́run. 27Ìwọ yóò gbàdúrà sí i, òun yóò sì gbọ́ ti rẹ, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ. 28Ohun tí ìwọ bá pinnu yóò ṣẹ, ìmọ́lẹ̀ yóò sì tàn sí ọ̀nà rẹ. 29Nígbà tí a bá rẹ àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀, tí ìwọ sì wí pé, ‘Gbé wọn sókè!’, òun yóò gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì là. 30Òun yóò gbà á là pàápàá ẹni tí kì í ṣe aláìlẹ́bi, ẹni tí a ó gbà là nípasẹ̀ mímọ́ ọwọ́ rẹ.”