Elihu Tún Sọ̀rọ̀
Elihu ṣàlàyé pé ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn àti ìwà rere ènìyàn kò yí ohunkóhun padà fún Ọlọ́run, ẹni tí ó ga ju ìkùukùu lọ; orí ènìyàn mìíràn ni wọ́n ń bọ́ sí. Àwọn tí a ń ni lára ń kígbe, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó béèrè pé níbo ni Ẹlẹ́dàá wọn wà, ẹni tí ń fúnni ní orin ní òru. Nítorí náà Jobu ń sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìní ìmọ̀.
35 1Nígbà náà ni Elihu tẹ̀síwájú, ó sì wí pé: 2“Ìwọ rò pé èyí tọ̀nà bí? Ìwọ wí pé, ‘Òdodo mi pọ̀ ju ti Ọlọ́run lọ.’ 3Nítorí ìwọ béèrè pé, ‘Èrè wo ni ó jẹ́ fún ọ? Kí ni mo jẹ ní èrè nípa àìdẹ́ṣẹ̀?’ 4Èmi yóò dá ọ lóhùn, àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ. 5Gbé ojú sókè wo àwọn ọ̀run kí o sì rí; tẹjú mọ́ àwọn àwọsánmà, tí ó ga ju ọ lọ. 6Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ ṣe sí i? Bí ìṣọ̀tẹ̀ rẹ bá sì pọ̀, kí ni ìwọ ṣe sí i? 7Bí ìwọ bá jẹ́ olódodo, kí ni ìwọ fi fún un? Tàbí kí ni ó rí gbà lọ́wọ́ rẹ? 8Ìwà búburú rẹ kàn ènìyàn bí ìwọ fúnra rẹ nìkan, òdodo rẹ sì kàn ọmọ ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ nìkan. 9Àwọn ènìyàn ké jáde lábẹ́ ìwúwo ìninilára púpọ̀; wọ́n ń pe fún ìrànlọ́wọ́ lòdì sí apá àwọn alágbára. 10Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà, ẹni tí ń fi orin fúnni ní òru, 11ẹni tí ń kọ́ wa ju àwọn ẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’ 12Níbẹ̀ ni wọ́n ké jáde, ṣùgbọ́n kò dáhùn, nítorí ìgbéraga àwọn ènìyàn búburú. 13Dájúdájú Ọlọ́run kì í fetí sí igbe òfo; Olódùmarè kì í fiyè sí i. 14Mélòó mélòó ni, nígbà náà, tí kì yóò dáhùn nígbà tí ìwọ wí pé ìwọ kò rí i—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀, ìwọ sì gbọ́dọ̀ dúró dè é. 15Nísinsìnyí, nítorí ìbínú rẹ̀ kò tíì fìyà jẹni, òun kò sì fiyè sí ìwà òmùgọ̀ púpọ̀. 16Jobu ya ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òfo; ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìní ìmọ̀.”