Àkójọpọ̀ Hesekáyà
Àwọn ènìyàn Hesekiah ni ó dà á kọ, ó sì kún fún àfiwé ju bí ó ti máa ń rí lọ: èso ápù wúrà, yìnyín ní àkókò ìkórè, eyín tí ó bàjẹ́, ọtí kíkan lórí sódà, ìlú tí kò ní odi. Ìmọ̀ràn rẹ̀ ṣe kedere, láti má ṣe ti ara rẹ síwájú níwájú ọba dé má ṣe pẹ́ jù ní ilé aládùúgbò rẹ.
25 1Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni òwe Solomoni, tí àwọn ọkùnrin Hesekáyà ọba Juda ṣẹ̀dà rẹ̀. 2Ògo Baba wa ni láti fi ọ̀ràn pamọ́, ṣùgbọ́n ògo àwọn ọba ni láti ṣàwárí ọ̀ràn. 3Bí ọ̀run ti ga tí ilẹ̀ ayé sì jìn, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn àwọn ọba kò ṣe é wádìí. 4Yọ ìdàrọ̀ kúrò nínú fàdákà, ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ. 5Yọ ẹni búburú kúrò níwájú ọba, ìtẹ́ rẹ̀ yóò sì fìdí múlẹ̀ nínú òdodo. 6Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe dúró ní ipò àwọn ẹni ńlá; 7nítorí ó sàn kí a sọ fún ọ pé, “Gòkè wá síhìn-ín,” ju kí a tẹ́ ọ sí ipò kékeré níwájú ọmọ ọlá tí ojú rẹ ń rí. 8Má ṣe sáré wọnú ìjà, nítorí kín ni ìwọ yóò ṣe níkẹyìn nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójú tì ọ́? 9Bá aládùúgbò rẹ jà ẹjọ́ rẹ fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn, 10kí ẹni tí ó bá gbọ́ ọ má bàa dójú tì ọ́, kí orúkọ búburú rẹ má sì kúrò láéláé. 11Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àsìkò tí ó yẹ dàbí èso wúrà nínú ìtẹ́ fàdákà. 12Bí òrùka wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n sí etí tí ń gbọ́rọ̀. 13Bí òtútù yìnyín ní àkókò ìkórè ni oníṣẹ́ olóòótọ́ sí àwọn tí ó rán an; ó tu ọkàn àwọn ọ̀gá rẹ̀ nínú. 14Bí àwọsánmà àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò ni ẹni tí ń ṣògo ẹ̀bùn tí kò fi fúnni rí. 15Nípa sùúrù ni à ń yí alákòóso padà lọ́kàn, ahọ́n pẹ̀lẹ́ sì ń ká egungun. 16Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ìwọ̀nba tí ó tó nìkan, kí ìwọ má bàa jẹ àjẹjù kí o sì bì í. 17Má ṣe lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbàgbogbo, kí ó má bàa sú u sí ọ kí ó sì kórìíra rẹ. 18Bí kùmọ̀, idà, àti ọfà mímú ni ẹni tí ó jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ̀. 19Bí eyín búburú tàbí ẹsẹ̀ tí ó yẹ̀ ni ìgbẹ́kẹ̀lé sí ẹni aláìṣòótọ́ ní àkókò ìpọ́njú. 20Bí ẹni tí ó bọ́ aṣọ rẹ̀ ní ọjọ́ òtútù, bí ọtí kíkan tí a dà sórí sódà, ni ẹni tí ń kọ orin fún ọkàn tí ó wúwo. 21Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ láti jẹ, bí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi láti mu; 22nítorí ìwọ yóò kó ẹ̀yín iná lé e lórí, Baba wa yóò sì san èrè fún ọ. 23Afẹ́fẹ́ àríwá a máa mú òjò wá, ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ níkọ̀kọ̀ sì ń mú ojú ìbínú wá. 24Ó sàn láti gbé ní igun òrùlé ju láti bá aya oníjà gbé ní ilé kan náà. 25Bí omi tútù sí ọkàn tí ó rẹ̀ ni ìhìnrere tí ó ti ilẹ̀ jíjìnnà wá. 26Bí ìsun tí a rú tàbí orísun tí a bà jẹ́ ni olódodo tí ó yẹ̀ níwájú ẹni búburú. 27Kì í ṣe ohun rere láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò dára láti wá ògo ara ẹni. 28Bí ìlú tí a ti wọ̀ tí a sì fi sílẹ̀ láìní odi ni ẹni tí kò lè kó ẹ̀mí ara rẹ̀ níjàánu.