Idà Baba Wa Bọ́ sórí Filistia
Ìkún omi Baba wa ru sókè láti àríwá sórí Filistia, lójijì tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn baba kò yíjú padà fún àwọn ọmọ wọn. Gasa àti Aṣkeloni ṣọ̀fọ̀. Ó parí pẹ̀lú bíbéèrè lọ́wọ́ idà pé yóò pẹ́ tó kí ó tó sinmi, ìdáhùn sì ni: kò ní sinmi níwọ̀n ìgbà tí ó ṣì ní àṣẹ.
47 1Ọ̀rọ̀ Baba wa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn ará Filistia, kí Farao tó kọlu Gasa.
2Báyìí ni Baba wa wí: “Ẹ wò ó, àwọn omi ń ru sókè láti àríwá, tí ó sì ń di ìkún-omi tí ń ru. Wọn yóò kún ilẹ̀ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, ìlú náà àti àwọn ènìyàn inú rẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò kígbe, gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà yóò sì hu. 3Nígbà tí ìró pátákò àwọn ẹṣin akọ rẹ̀ bá dún, nígbà tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń hó àti kíkùn àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àwọn baba kì yóò yípadà fún àwọn ọmọ wọn, ọwọ́ wọn yóò sì rọ, 4nítorí ọjọ́ náà tí ń bọ̀ láti pa gbogbo àwọn ará Filistia run, láti ké kúrò ní Tire àti Sidoni gbogbo ẹni tí ó ṣẹ́kù tí ó lè ṣèrànwọ́. Nítorí Baba wa ń pa àwọn ará Filistia run, àwọn ìyókù láti etí òkun Kaftori. 5Gasa yóò fá orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀; Aṣkeloni yóò dákẹ́ rọ́rọ́. Ẹ̀yin ìyókù àfonífojì wọn, yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa sá ara yín lọ́gbẹ́? 6Á à, ìdà Baba wa! Yóò ti pẹ́ tó kí o tó sinmi? Padà sínú akọ̀ rẹ; dúró jẹ́ẹ́, kí o sì wà ní àlàáfíà. 7Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi nígbà tí Baba wa ti pa á láṣẹ? Lòdì sí Aṣkeloni àti lòdì sí etí òkun—ibẹ̀ ni ó ti darí rẹ̀ sí.”