Fa Ọ̀run Ya
Èyí jẹ́ àdúrà pé kí Baba wa fa ojú ọ̀run ya kí ó sì sọ̀kalẹ̀. Kò gbèjà àwọn ènìyàn; ó pe iṣẹ́ rere wọn tí ó dára jù ní aṣọ ẹlẹ́gbin, ó sì gbà pé kò sí ẹni tí ó di òun mú. Tẹ́ńpìlì ti jóná. Ó parí lórí ìbéèrè tí a kò dáhùn.
64 1Háà, ìbá ṣe pé ìwọ yóò fa ọ̀run ya, kí o sì sọ̀kalẹ̀, kí àwọn òkè ńlá lè wárìrì níwájú rẹ, 2bí iná ti ń fi igi gbígbẹ jó, tí ó sì ń mú omi hó—láti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ọ̀tá rẹ, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè wárìrì níwájú rẹ! 3Nígbà tí ìwọ ṣe àwọn ohun amúnimọ́lẹ̀ tí àwa kò retí, ìwọ sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ. 4Láti ìgbà àtijọ́, kò sí ẹni tí ó ti gbọ́ tàbí tí ó fi etí dámọ̀, ojú kankan kò ì tí ì rí ẹnìkan yàtọ̀ sí ìwọ, ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ fún ẹni tí ń dúró dè é. 5Ìwọ ń tẹ́wọ́gba àwọn tí ń fi ayọ̀ ṣe ohun tí ó tọ́, àwọn tí ń rántí rẹ bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà rẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ bínú, àwa sì dẹ́ṣẹ̀; ó ti pẹ́ tí àwa ti wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa—ṣé a lè ní ìgbàlà? 6Gbogbo wa ti dàbí ẹni tí kò mọ́, gbogbo iṣẹ́ òdodo wa sì dàbí aṣọ eléèérí. Gbogbo wa sì ṣá bí ewé, ẹ̀ṣẹ̀ wa sì, bí afẹ́fẹ́, gbá wa lọ. 7Kò sí ẹni tí ń ké pe orúkọ rẹ, tí ó jí ara rẹ̀ láti dì ọ́ mú; nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa, ìwọ sì ti fi wá lé ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ́wọ́.
8Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ìwọ ni Baba wa; àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni amọ̀kòkò wa; gbogbo wa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 9Má ṣe bínú kíkorò tó bẹ́ẹ̀, Baba wa, má sì ṣe rántí ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé. Wò wá, jọ̀wọ́—gbogbo wa ni ènìyàn rẹ. 10Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀; Sioni ti di aṣálẹ̀, Jerusalemu sì ti di ahoro. 11Ilé mímọ́ àti ẹlẹ́wà wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, ni a ti fi iná sun, gbogbo ohun tí àwa fẹ́ràn sì ti di ahoro. 12Lẹ́yìn gbogbo èyí, ṣé ìwọ yóò fàsẹ́yìn, Baba wa? Ṣé ìwọ yóò dákẹ́, kí o sì pọ́n wa lójú tó bẹ́ẹ̀?