Kò Sí Ẹni Tí Ń Ṣe Rere
Fún aṣáájú orin, gẹ́gẹ́ bí Mahalati. Orin ọgbọ́n ti Dafidi.
Ó fẹ́rẹ̀ jọ Orin Dafidi 14 pátápátá. Baba wa bojú wo gbogbo ọmọ èèyàn, ó ń wá ẹnìkan tí ó ní òye, kò sì rí ẹnìkan. Ẹ̀rù bo àwọn tí ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ run níbi tí kò sí ohun ẹ̀rù. Ó parí pẹ̀lú ìfẹ́ àtọkànwá fún ìgbàlà láti Sioni wá.
53 1Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Kò sí Ọlọ́run.” Wọ́n ti díbàjẹ́, wọ́n ń ṣe ohun ìríra; kò sí ẹni tí ń ṣe rere.
2Baba wa síjú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí gbogbo ọmọ ènìyàn láti wò bóyá ẹnikẹ́ni wà tí ó ní òye, ẹnikẹ́ni tí ó ń wá a. 3Gbogbo wọn ti ṣáko lọ; papọ̀ ni wọ́n ti díbàjẹ́; kò sí ẹni tí ń ṣe rere, kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan.
4Ṣé àwọn oníṣẹ́ ibi kò ní ìmọ̀—àwọn tí ń jẹ àwọn ènìyàn mi run bí wọ́n ti ń jẹ àkàrà, tí wọn kò sì ké pe Baba wa? 5Ibẹ̀ ni ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, níbi tí kò ti sí ohun tí a ó bẹ̀rù; nítorí Baba wa fọ́n egungun ẹni tí ó dó ti ọ ká; ìwọ ti dójú tì wọ́n, nítorí Baba wa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
6Hà, ìbá ṣe pé ìgbàlà fún Israẹli yóò ti Sioni jáde wá! Nígbà tí Baba wa bá dá ọrọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, kí Jakọbu yọ̀, kí inú Israẹli dùn.