Ìwé Kíká tí Ó Dùn bí Oyin
Ó jẹ ìwé kíká náà, ó sì dùn bí oyin, lẹ́yìn náà a gbé e lọ sọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn ní Teli-abibu, níbi tí ó jókòó láàrin wọn ní ìyàlẹ́nu fún ọjọ́ méje. Baba wa fi í ṣe olùṣọ́, tí yóò jíhìn nípa ìkìlọ̀, lẹ́yìn náà ó di ahọ́n rẹ̀ kí ó lè sọ̀rọ̀ kìkì nígbà tí a bá fún un ní ọ̀rọ̀.
3 1Ó wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ìwọ bá rí. Jẹ ìwé kíká yìí, kí o sì lọ bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”
2Mo sì ya ẹnu mi, ó sì fún mi ní ìwé kíká yìí láti jẹ.
3Ó wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, fi ìwé kíká yìí tí mò ń fún ọ bọ́ inú rẹ, kí o sì fi kún ikùn rẹ.” Mo sì jẹ ẹ́, ó sì dùn ní ẹnu mi bí oyin.
4Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, lọ bá ilé Israẹli, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn.
5“Nítorí a kò rán ọ sí àwọn ènìyàn tí ọ̀rọ̀ wọn ṣòro àti tí èdè wọn nira, bí kò ṣe sí ilé Israẹli, 6kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ọ̀rọ̀ wọn ṣòro àti tí èdè wọn le, tí ìwọ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Nítòótọ́, ìbá ṣe pé mo rán ọ sí wọn, wọn ìbá tẹ́tí sí ọ. 7Ṣùgbọ́n ilé Israẹli kì yóò fẹ́ gbọ́ tìrẹ, nítorí wọn kò fẹ́ gbọ́ tèmi; nítorí gbogbo ilé Israẹli ní orí líle, wọ́n sì ṣe agídí ọkàn. 8Wò ó, mo ti sọ ojú rẹ di líle gẹ́gẹ́ bí ojú wọn, àti iwájú orí rẹ di líle gẹ́gẹ́ bí iwájú orí wọn. 9Mo ti sọ iwájú orí rẹ dàbí òkúta líle, tí ó le ju òkúta akọ lọ. Má bẹ̀rù wọn, bẹ́ẹ̀ ni kí ìrísí wọn má ba inú rẹ jẹ́, nítorí ilé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”
10Ó wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gba gbogbo ọ̀rọ̀ mi tí mo bá sọ fún ọ sí ọkàn rẹ, kí o sì fi etí rẹ gbọ́ wọn. 11Lọ bá àwọn ìgbèkùn, àwọn ènìyàn tìrẹ, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀. Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Baba Olódùmarè wí,’ ìbáà ṣe pé wọ́n gbọ́ tàbí kí wọ́n kọ̀ láti gbọ́.”
12Nígbà náà ni Ẹ̀mí Baba wa gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ìró ńlá tí ń dún lẹ́yìn mi pé: “Ìbùkún ni fún ògo Baba wa láti ibùjókòó rẹ̀!” 13ìró ìyẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń fọwọ́ pa ara wọn, àti ìró àwọn kẹ̀kẹ́ tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ìró ńlá tí ń dún. 14Ẹ̀mí náà gbé mi sókè, ó sì gbé mi lọ, mo sì lọ pẹ̀lú ìkorò, ẹ̀mí mi sì ń jó nínú mi, ọwọ́ Baba wa sì lágbára lórí mi. 15Mo wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ìgbèkùn ní Teli-abibu lẹ́bàá odò Kebari, mo sì jókòó láàrin wọn níbẹ̀, pẹ̀lú ìdààmú ọkàn, fún ọjọ́ méje.
Baba Yan Olùṣọ́ Kan
16Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ọ̀rọ̀ Baba wa tọ̀ mí wá pé:
17“Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu mi, kìlọ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ mi. 18Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ tí o kò sì kìlọ̀ fún un tàbí sọ̀rọ̀ láti kìlọ̀ fún ènìyàn búburú náà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.
19“Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí kò sì yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀ tàbí ọ̀nà búburú rẹ̀, yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ yóò ti gba ẹ̀mí ara rẹ là.
20“Síwájú sí i, nígbà tí olódodo kan bá yípadà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí ó sì ṣe búburú, tí mo sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ sí iwájú rẹ̀, yóò kú. Nítorí tí o kò kìlọ̀ fún un, yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kì yóò sì rántí àwọn iṣẹ́ òdodo rẹ̀, èmi yóò sì béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. 21Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, yóò yè nítorí tí ó gbọ́ ìkìlọ̀ náà, ìwọ yóò sì ti gba ẹ̀mí ara rẹ là.”
22Ọwọ́ Baba wa sì wà lórí mi níbẹ̀, ó sì wí fún mi pé, “Dìde, jáde lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀.”
23Mo sì dìde, mo sì lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni ògo Baba wa sì dúró, gẹ́gẹ́ bí ògo tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari, mo sì dojúbolẹ̀.
24Ẹ̀mí náà sì wọ inú mi, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé: “Lọ, tì ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ. 25Ìwọ, ọmọ ènìyàn, wọn yóò sì fi okùn dì ọ́, wọn yóò sì fi wọ́n dè ọ́, tí ìwọ kì yóò lè jáde lọ sí àárín àwọn ènìyàn.
26Èmi yóò sì mú ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ; ìwọ yóò di odi, ìwọ kì yóò lè bá wọn wí, nítorí ilé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. 27Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀, èmi yóò ya ẹnu rẹ, ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Baba Olódùmarè wí.’ Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbọ́, kí ó gbọ́; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kọ̀, kí ó kọ̀—nítorí ilé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”