Rabba Ṣubú, Dafidi sì Wọ Adé
Jóábù ni ó ja ogun ní Rábà nígbà tí Dáfídì dúró sílé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé níhìn-ín ọba dé láti gba adé. Lẹ́yìn náà ìjà kéékèèké mẹ́ta pẹ̀lú àwọn òmìrán Filísínì, títí kan ọkùnrin kan tí ó ní ìka mẹ́fà tí ó fi Ísírẹ́lì ṣẹ̀sín, tí ọmọ arákùnrin Dáfídì sì pa.
20 1Ní ìyípadà ọdún, nígbà tí àwọn ọba a máa jáde lọ sí ogun, Joabu mú ọmọ ogun jáde, ó sì fọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ammoni túútúú, lẹ́yìn náà ó wá dó ti Rabba, nígbà tí Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Joabu sì kọlu Rabba, ó sì wó o palẹ̀. 2Dafidi sì gba adé kúrò ní orí ọba wọn. Ìwọ̀n rẹ̀ tó nǹkan bí àrùndínlọ́gọ́rin pọ́ńdù wúrà, a sì fi òkúta iyebíye ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, a sì gbé e ka orí Dafidi. Ó sì kó ìkógun púpọ̀ jáde kúrò ní ìlú náà. 3Ó sì mú àwọn ènìyàn inú rẹ̀ jáde, ó sì fi wọ́n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ayùn, àti ohun ìwalẹ̀ irin, àti àáké. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ammoni. Nígbà náà Dafidi àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ padà sí Jerusalẹmu.
Àwọn Òmìrán Ṣubú ní Ọwọ́ Israẹli
4Lẹ́yìn èyí, ogun bẹ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn Filistini ní Geseri. Ní àkókò náà Sibbekai ará Huṣa pa Sippai, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Rafa, a sì ṣẹ́gun àwọn Filistini.
5Ogun sì tún bẹ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn Filistini. Elhanani ọmọ Jairi pa Lahmi, arákùnrin Goliati ará Gati, ẹni tí igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ tóbi bí ìtì igi wíwúwo. 6Ogun sì tún bẹ́ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ní Gati, níbi tí ọkùnrin ńlá kan wà, tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan àti ìka mẹ́fà ní ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan, mẹ́rìnlélógún lápapọ̀—òun náà ni a bí fún Rafa. 7Nígbà tí ó fi Israẹli ṣe ẹlẹ́yà, Jonatani ọmọ Ṣimea, arákùnrin Dafidi, pa á. 8Àwọn wọ̀nyí ni a bí fún Rafa ní Gati, wọ́n sì ṣubú ní ọwọ́ Dafidi àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.