Ẹ Péjọ Kí Ìjì Náà Tó Dé
Ìpè náà ni pé kí wọ́n kó ara jọ kí ìbínú Baba wa àti àṣẹ rẹ̀ tó dé, ìrètí kan ṣoṣo tí a sì fi lélẹ̀ ni 'bóyá' — ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀, bóyá a ó fi yín pamọ́. Lẹ́yìn náà a dárúkọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, títí dé Nineve agbéraga, tí ó dá ara rẹ̀ lójú, tí a fi sílẹ̀ ní ahoro.
2 1Ẹ péjọ, ẹ kó ara yín jọ, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè aláìlójútì, 2kí àṣẹ náà tó bí—ọjọ́ náà ń kọjá bí ìyàngbò—kí ìbínú gbígbóná Baba wa tó dé bá yín, kí ọjọ́ ìbínú Baba wa tó dé bá yín. 3Ẹ wá Baba wa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, tí ẹ ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀. Bóyá a ó fi yín pamọ́ ní ọjọ́ ìbínú Baba wa. 4Nítorí a ó kọ Gasa sílẹ̀, Aṣkeloni yóò sì di ahoro; a ó lé Aṣdodu jáde ní ọ̀sán gangan, a ó sì fa Ekroni tu. 5Ègbé ni fún yín tí ẹ ń gbé létí òkun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè àwọn ara Kereti! Ọ̀rọ̀ Baba wa dojú ìjà kọ yín, ìwọ Kenaani, ilẹ̀ àwọn Filistini pé: “Èmi yóò pa yín run títí kì yóò fi sí olùgbé kankan tí yóò kù.” 6Etíkun òkun yóò sì di pápá oko, pẹ̀lú pápá fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agọ́ fún agbo ẹran. 7Etíkun náà yóò jẹ́ ti àwọn àṣẹ́kù ilé Juda; níbẹ̀ ni wọn yóò ti máa jẹ, nínú àwọn ilé Aṣkeloni ni wọn yóò sì dùbúlẹ̀ ní àṣálẹ́. Nítorí Baba wa yóò ṣọ́ wọn, yóò sì mú ìre wọn padà bọ̀sípò. 8Mo ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu àti ẹ̀sín àwọn ọmọ Ammoni, tí wọ́n fi gàn àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ṣe ìgbéraga lórí ilẹ̀ wọn.
9Nítorí náà, bí mo ti wà láàyè, ni Baba àwọn ọmọ ogun ọ̀run wí, Baba wa ti Israẹli, Moabu yóò dàbí Sodomu, àwọn ọmọ Ammoni yóò sì dàbí Gomorra— ilẹ̀ ẹ̀gún àti ihò iyọ̀, ahoro títí láéláé. Àwọn àṣẹ́kù ènìyàn mi yóò kó wọn, àwọn ìyókù orílẹ̀-èdè mi yóò sì jogún wọn. 10“Èyí ni ohun tí wọn yóò rí gbà nítorí ìgbéraga wọn, nítorí tí wọ́n gàn, tí wọ́n sì ṣe ìgbéraga sí àwọn ènìyàn Baba àwọn ọmọ ogun ọ̀run. 11Baba wa yóò jẹ́ olùpáyà fún wọn, nítorí yóò fi ebi pa gbogbo òrìṣà ayé; gbogbo etíkun àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì foríbalẹ̀ fún un, olúkúlùkù láti ibùgbé rẹ̀ wá.”
12Ẹ̀yin ara Kuṣi pẹ̀lú, a ó fi idà mi pa yín.
13Yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí ìhà àríwá, yóò sì pa Assiria run, yóò sì sọ Ninefe di ahoro, gbígbẹ bí aṣálẹ̀. 14Agbo ẹran yóò dùbúlẹ̀ ní àárín rẹ̀, oríṣiríṣi ẹranko igbó; àti òwìwí àti ọ̀gọ̀ngọ̀ yóò máa gbé lórí orí àwọn òpó rẹ̀. Ohùn kan yóò máa kọrin nínú àwọn fèrèsé, àlàpà yóò wà ní ìloro ẹnu-ọ̀nà, nítorí tí a ti bọ́ iṣẹ́ igi kedari sílẹ̀. 15Èyí ni ìlú aláìníyọnu tí ó gbé ní àìléwu, tí ó wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.” Ẹ wo bí ó ti di ahoro tó, ihò fún àwọn ẹranko igbó! Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò máa súfèé, yóò sì gbọn ọwọ́ rẹ̀.