Baba Fà Sẹ́yìn Kúrò Lọ́dọ̀ Àwọn Aláìṣòótọ́
A pe àwọn àlùfáà, ọba àti orílẹ̀-èdè lápapọ̀. Ìṣe wọn kò jẹ́ kí wọ́n padà, nígbà tí wọ́n sì lọ wá a pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ màlúù, Baba wa ti fà sẹ́yìn. Ó pe ara rẹ̀ ní ìjẹrà sí Juda àti kìnnìún sí Efraimu, lẹ́yìn náà ó lọ títí ìpọ́njú yóò fi lé wọn padà.
5 1Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin àlùfáà! Ẹ fetí sílẹ̀, ilé Israẹli! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ilé ọba! Nítorí ìdájọ́ náà jẹ́ fún yín, nítorí ẹ ti jẹ́ ìdẹkùn ní Mispa àti àwọ̀n tí a nà lórí Tabori.
2“Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti jìn jìnnà sínú ìpànìyàn, ṣùgbọ́n èmi yóò bá gbogbo wọn wí. 3Èmi mọ Efraimu, Israẹli kò sì fi ara pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi; nítorí nísinsìnyí, Efraimu, ìwọ ti ṣe àgbèrè, Israẹli sì ti di aláìmọ́.
4“Àwọn iṣẹ́ wọn kì yóò jẹ́ kí wọn padà sọ́dọ̀ Baba wọn, nítorí ẹ̀mí àgbèrè ń bẹ nínú wọn, wọn kò sì mọ Baba wa. 5Ìgbéraga Israẹli jẹ́rìí lòdì sí i; Israẹli àti Efraimu kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn; Juda pẹ̀lú sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn. 6Pẹ̀lú agbo àgùntàn wọn àti agbo màlúù wọn ni wọn yóò lọ wá Baba wa kiri, ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i; ó ti fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wọn. 7Wọn ti ṣe àìṣòótọ́ sí Baba wa, nítorí wọn ti bí àwọn ọmọ àlè. Nísinsìnyí oṣù tuntun yóò jẹ wọn run pẹ̀lú oko wọn.
8“Ẹ fọn ìwo ní Gibea, ìpè ní Rama. Ẹ ké igbe ogun ní Beti-afeni; wo ẹ̀yìn rẹ, Benjamini! 9Efraimu yóò di ahoro ní ọjọ́ ìjìyà; nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli ni mo sọ ohun tí ó dájú di mímọ̀. 10Àwọn ọmọ-ọba Juda ti dàbí àwọn tí ń ṣí òkúta ààlà; sórí wọn ni èmi yóò tú ìbínú mi jáde bí omi. 11Efraimu ni a ni lára, a sì tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀ nínú ìdájọ́, nítorí ó pinnu láti máa lépa àwọn òrìṣà asán. 12Nítorí náà, èmi dàbí kòkòrò aṣọ fún Efraimu, àti bí ìjẹrà fún ilé Juda.
13“Efraimu rí àìsàn ara rẹ̀, Juda sì rí egbò rẹ̀ tí ó ṣí sílẹ̀; nítorí náà Efraimu sáré lọ sí Asiria, ó ránṣẹ́ sí ọba ńlá rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọba náà kò lè wò ọ́ sàn, bẹ́ẹ̀ ni kò lè mú ọgbẹ́ rẹ tí ń jó sàn. 14Nítorí èmi yóò dàbí kìnnìún fún Efraimu, àti bí ọmọ kìnnìún fún ilé Juda. Èmi tìkára mi yóò fàya, èmi yóò sì lọ; èmi yóò gbé e lọ, kì yóò sì sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀. 15Èmi yóò padà lọ sí ibùjókòó mi lẹ́ẹ̀kan sí i, títí wọn yóò fi jẹ́wọ́ ẹ̀bi wọn tí wọn yóò sì wá ojú mi; nínú ìpọ́njú wọn, wọn yóò fi ìtara wá mi.”