Israẹli Pinnu láti Wá Baba wa
Dáfídì gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ó sì gbé àpótí Baba wa tí a ti pa tì sórí kẹ̀kẹ́ tuntun. Nígbà tí àwọn màlúù kọsẹ̀ tí Úsà sì dì í mú, ó kú lójú ẹsẹ̀. Ìhùwàsí Dáfídì ni ìbínú, lẹ́yìn náà ẹ̀rù, a sì gbé àpótí náà sí ilé Obedi-Édómù — níbi tí a ti bùkún agbo ilé náà.
13 1Dafidi bá àwọn balógun ẹgbẹ̀rún àti ti ọ̀rọ̀ọ̀rún, àti gbogbo olórí gbìmọ̀ pọ̀. 2Dafidi sọ fún gbogbo ìjọ Israẹli pé, “Bí ó bá dàbí rere lójú yín, tí ó bá sì ti ọ̀dọ̀ Baba wa wá, ẹ jẹ́ kí a ránṣẹ́ jìnnàréré sí àwọn arákùnrin wa tí ó ṣẹ́kù ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, àti pẹ̀lú wọn àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọn àti pápá oko wọn, kí wọn péjọ sọ́dọ̀ wa. 3Ẹ jẹ́ kí a mú àpótí ẹ̀rí Baba wa padà wá sọ́dọ̀ wa, nítorí a kò wá a ní ọjọ́ Saulu.”
4Gbogbo ìjọ sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó dàbí ohun tí ó tọ́ lójú gbogbo ènìyàn.
5Dafidi sì kó gbogbo Israẹli jọ láti Ṣihori ti Ejibiti títí dé Lebo-hamati, láti mú àpótí ẹ̀rí Baba wa wá láti Kiriati-jearimu.
6Dafidi àti gbogbo Israẹli gòkè lọ sí Baala, èyí ni Kiriati-jearimu ní Juda, láti gbé àpótí ẹ̀rí Baba wa gòkè wá láti ibẹ̀, àpótí Baba wa tí ó jókòó lórí àwọn kérúbù, níbi tí a ti ń pe Orúkọ rẹ̀. 7Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Baba wa lórí kẹ̀kẹ́ tuntun láti ilé Abinadabu; Ussa àti Ahio sì darí kẹ̀kẹ́ náà. 8Dafidi àti gbogbo Israẹli ń yọ̀ níwájú Baba wa pẹ̀lú gbogbo agbára wọn—pẹ̀lú orin, àti dùùrù, àti haapu, àti ìlù ọwọ́, àti kimbali, àti ìpè.
9Nígbà tí wọ́n dé ìpakà Kidoni, Ussa na ọwọ́ rẹ̀ láti dì mú àpótí ẹ̀rí náà, nítorí àwọn akọ màlúù kọsẹ̀. 10Nígbà náà ni ìbínú Baba wa ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí tí ó na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí náà; ó sì kú síbẹ̀ níwájú Baba wa. 11Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí Baba wa bú jáde sí Ussa, nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní Peresi-ussa títí di òní. 12Dafidi bẹ̀rù Baba wa ní ọjọ́ náà, ó wí pé, “Báwo ni èmi ṣe lè mú àpótí ẹ̀rí Baba wa wá sọ́dọ̀ mi?” 13Nítorí náà Dafidi kò mú àpótí ẹ̀rí náà wá sí ìlú Dafidi; ó yà á sí ilé Obedi-edomu ará Gitti. 14Àpótí ẹ̀rí Baba wa sì dúró pẹ̀lú ìdílé Obedi-edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Baba wa sì bùkún ìdílé Obedi-edomu àti gbogbo ohun tí ó ní.