Ẹni Tí Ó Di Àwọn Ìràwọ̀ Mú
Jesu ń sọ lẹ́tà mẹ́rin kí a kọ wọ́n sílẹ̀. Efesu ń ṣiṣẹ́ kára ṣùgbọ́n ó ti fi ìfẹ́ tí ó ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀. Smirna jẹ́ tálákà, wọ́n sì fẹ́ sọ ọ́ sínú túbú. Pergamu ń gba ẹ̀kọ́ Balaamu láàyè, Tiatira sì ń gba Jesebeli láàyè. Ó dárúkọ àṣìṣe ìjọ kọ̀ọ̀kan, lẹ́yìn náà ó ṣe ìlérí igi ìyè nínú párádísè Baba wa.
2 1“Sí angẹli ìjọ tí ń bẹ ní Efesu kọ̀wé pé: Ẹni tí ó di ìràwọ̀ méje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó sì ń rìn láàrín ọ̀pá fìtílà wúrà méje, wí báyìí pé:
2“Èmi mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, làálàá rẹ, àti sùúrù rẹ, àti pé ìwọ kò lè faradà àwọn ènìyàn búburú; ìwọ dán àwọn tí ń pe ara wọn ní àpọ́sítélì wò ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ sì rí wọn pé òpùrọ́ ni wọ́n. 3Ìwọ ti ní sùúrù, o sì ti faradà nítorí orúkọ mi, o kò sì rẹ̀wẹ̀sì. 4Ṣùgbọ́n èyí ni mo ní lòdì sí ọ: ìwọ ti kọ ìfẹ́ tí o ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀. 5Nítorí náà, rántí ibi tí o ti ṣubú kúrò; ronú pìwàdà kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ àkọ́kọ́ rẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ láti mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀—àyàfi bí o bá ronú pìwàdà. 6Ṣùgbọ́n ìwọ ní èyí: ìwọ kórìíra àwọn iṣẹ́ àwọn ọmọ Nikolasi, tí èmi náà kórìíra. 7Ẹnikẹ́ni tí ó ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ wí fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fún láti jẹ nínú igi ìyè tí ń bẹ nínú Párádísè Baba wa.
Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn
8“Sí angẹli ìjọ tí ń bẹ ní Smirna kọ̀wé pé: Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn, ẹni tí ó kú tí ó sì tún wà láàyè, wí báyìí pé:
9“Èmi mọ ìpọ́njú rẹ àti òṣì rẹ—síbẹ̀ ọlọ́rọ̀ ni ìwọ—àti ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, sinagọgu Satani ni wọ́n. 10Má bẹ̀rù ohun tí o fẹ́ máa jìyà rẹ̀. Èṣù yóò sọ àwọn kan nínú yín sínú túbú láti dán yín wò; ìwọ yóò jìyà fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olóòótọ́ títí dé ikú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè. 11Ẹnikẹ́ni tí ó ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, ikú kejì kì yóò pa á lára.
Idà Olójú Méjì Mímú
12“Sí angẹli ìjọ tí ń bẹ ní Pergamu kọ̀wé pé: Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní idà olójú méjì mímú:
13“Èmi mọ ibi tí o ń gbé—níbi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú, ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi rí, àní nígbà tí a pa Antipa, ẹlẹ́rìí mi olóòótọ́, láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé. 14Ṣùgbọ́n ohun díẹ̀ ni mo ní lòdì sí ọ: àwọn kan níbẹ̀ di ẹ̀kọ́ Balaamu mú. Ó kọ́ Balaki láti gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ níwájú Israẹli, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti láti dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè. 15Bákan náà, ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ Nikolasi mú. 16Nítorí náà, ronú pìwàdà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò tọ̀ ọ́ wá láìpẹ́, èmi yóò sì fi idà ẹnu mi bá àwọn tí ó dì í mú jà. 17Ẹnikẹ́ni tí ó ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fún ní manna tí a fi pamọ́ àti òkúta funfun kan tí a kọ orúkọ tuntun sí, tí kò sí ẹni tí ó mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.
Ojú Bí Ọwọ́ Iná
18“Sí angẹli ìjọ tí ń bẹ ní Tiatira kọ̀wé pé: Ọmọ Baba wa, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọwọ́ iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dídán, wí báyìí pé:
19“Èmi mọ àwọn iṣẹ́ rẹ—ìfẹ́ rẹ, ìgbàgbọ́ rẹ, iṣẹ́ ìsìn rẹ, àti sùúrù rẹ—àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ìkẹyìn ju ti àkọ́kọ́ lọ. 20Ṣùgbọ́n èyí ni mo ní lòdì sí ọ: ìwọ fàyè gba obìnrin náà Jesebeli, ẹni tí ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì, tí ń kọ́ni tí ó sì ń ṣì àwọn ìránṣẹ́ mi lọ́nà sínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè àti jíjẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìṣà. 21Mo fún un ní àkókò láti ronú pìwàdà, ṣùgbọ́n kò fẹ́ ronú pìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀. 22Èmi yóò sọ ọ́ sórí àkéte àìsàn, àti àwọn tí ó bá a ṣe panṣágà sínú ìpọ́njú ńlá, àyàfi bí wọ́n bá yípadà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 23Èmi yóò sì fi ikú kọlu àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà náà, gbogbo àwọn ìjọ yóò mọ̀ pé èmi ni ẹni tí ń wá inú ọkàn àti àyà, èmi yóò sì san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gẹ́gẹ́ bí àwọn iṣẹ́ yín. 24Ṣùgbọ́n sí ìyókù yín ní Tiatira tí kò di ẹ̀kọ́ yìí mú, tí kò kọ́ ohun tí a ń pè ní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Satani: èmi kò gbé ẹrù mìíràn lé e yín lórí. 25Ẹ kàn di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí èmi yóò fi dé. 26Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, tí ó sì pa àwọn iṣẹ́ mi mọ́ dé òpin, èmi yóò fún un ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, 27yóò sì fi ọ̀pá irin ṣàkóso wọn, yóò sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀—gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti gba àṣẹ lọ́wọ́ Baba mi. 28Èmi yóò sì fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀. 29Ẹnikẹ́ni tí ó ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ wí fún àwọn ìjọ.”