Wá A Bí Fàdákà
Àríyànjiyàn náà ní àdéhùn. Bí o bá lépa òye bí ènìyàn ti ń wa fàdákà tí a bò mọ́lẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ ohun tí ìbẹ̀rù Baba wa túmọ̀ sí. Èrè rẹ̀ wúlò: ààbò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tí inú wọn ń dùn láti ṣe ibi, àti lọ́wọ́ àjèjì tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dùn mọ̀ràn-ìn-mọran-in.
2 1Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì to àṣẹ mi jọ sínú rẹ, 2tí ìwọ bá dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, tí ìwọ sì yí ọkàn rẹ padà sí òye; 3bẹ́ẹ̀ ni, bí ìwọ bá ké pe làákàyè, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye, 4bí ìwọ bá wá a bí fàdákà, tí ìwọ sì wá a bí ìṣúra tí a fi pamọ́, 5nígbà náà ni ìwọ yóò wá mọ ìbẹ̀rù Baba wa, tí ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Baba wa. 6Nítorí Baba wa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti òye ti ń jáde. 7Ó to ọgbọ́n tí ó yè kooro jọ fún àwọn olódodo; òun ni asà fún àwọn tí ń rìn ní ìdúró ṣinṣin, 8ó ń ṣọ́ ọ̀nà ìdájọ́ òdodo, ó sì ń ṣọ́ ipa ọ̀nà àwọn olóòtítọ́ rẹ̀.
9Nígbà náà ni ìwọ yóò wá mọ òdodo àti ìdájọ́ òtítọ́ àti àìṣègbè—gbogbo ọ̀nà rere. 10Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóò sì dùn mọ́ ẹ̀mí rẹ; 11ọgbọ́n-inú yóò máa ṣọ́ ọ, òye yóò sì máa dáàbò bò ọ́, 12ó ń gbà ọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọ̀nà ibi, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń sọ ọ̀rọ̀ wíwọ́, 13àwọn tí wọ́n kọ ọ̀nà ìdúró ṣinṣin sílẹ̀, láti máa rìn ní ọ̀nà òkùnkùn, 14àwọn tí inú wọn ń dùn láti ṣe ibi, tí wọ́n sì ń yọ̀ sí ìwà òdì ibi, 15àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́, tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ipa ọ̀nà wọn.
16Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú lọ́wọ́ obìnrin èèwọ̀, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ dídùn ẹnu rẹ̀ tannijẹ, 17ẹni tí ó kọ ẹnìkejì ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú Baba rẹ̀. 18Nítorí ilé rẹ̀ ń wó lọ sínú ikú, ọ̀nà rẹ̀ sì ń lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òkú. 19Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ ọ́ lọ tí ó padà bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ipa ọ̀nà ìyè.
20Nítorí náà ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni rere, tí ìwọ yóò sì tẹ̀lé ipa ọ̀nà àwọn olódodo. 21Nítorí àwọn olódodo yóò máa gbé ní ilẹ̀ náà, àwọn tí ìwà wọn dúró ṣinṣin yóò sì kù sínú rẹ̀; 22ṣùgbọ́n a ó ké àwọn ènìyàn búburú kúrò ní ilẹ̀ náà, a ó sì fa àwọn ẹlẹ́tàn tu kúrò nínú rẹ̀.