Ó Jókòó Lórí Ìtẹ́
Ẹ̀ẹ̀mẹta ni psalmu náà dúró láti sọ pé, mímọ́ ni òun. Baba wa, Ọba tí ó ń mì ayé, tún fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, àwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ sì ni Mose, Aaroni àti Samueli — àwọn tí ó dá lóhùn láti inú ọ̀wọ̀n ìkùukùu, tí ó dárí jì, tí ó sì tún mú jíhìn.
99 1Baba wa ń jọba; kí àwọn ènìyàn kí ó wárìrì! Ó jókòó lórí ìtẹ́ lókè àwọn kérúbù; kí ayé kí ó mì tìtì! 2Baba wa tóbi ní Sioni; a gbé e ga ju gbogbo àwọn ènìyàn lọ. 3Kí wọn kí ó yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù; mímọ́ ni òun!
4Ọba alágbára fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́. Ìwọ ti fi ìdọ́gba kalẹ̀; ìwọ ti mú ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo wá ní Jakọbu. 5Ẹ gbé Baba wa ga; ẹ foríbalẹ̀ ní ìtẹ̀sẹ̀ rẹ̀! Mímọ́ ni òun!
6Mose àti Aaroni wà lára àwọn àlùfáà rẹ̀, Samueli sì wà lára àwọn tí ń ké pe orúkọ rẹ̀. Wọ́n ké pe Baba wa, ó sì dá wọn lóhùn. 7Láti inú ọ̀wọ́n ìkùukùu ni ó sọ̀rọ̀ sí wọn; wọ́n pa àwọn òfin rẹ̀ àti àwọn ìlànà tí ó fún wọn mọ́.
8Baba wa, ìwọ dá wọn lóhùn; ìwọ jẹ́ Baba tí ń dárí jì wọ́n, síbẹ̀ ìwọ bá wọn wí nítorí àwọn ìwà búburú wọn. 9Ẹ gbé Baba wa ga, kí ẹ sì foríbalẹ̀ ní òkè mímọ́ rẹ̀; nítorí mímọ́ ni Baba wa!