Títóbi Mordekai
Ọ̀rọ̀ ìparí ẹsẹ mẹ́ta ní ọ̀nà ìwé ìrántí ọba: ọba gba owó òde káàkiri ilẹ̀ àti etíkun, a sì ń rántí Mordekai, tí ó wà ní ipò kejì sí ìtẹ́ báyìí, nítorí pé ó lo agbára náà láti wá ire àwọn ènìyàn rẹ̀ àti láti sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún àwọn tirẹ̀.
10 1Ọba Ahaswerusi sì fi owó òde lé ilẹ̀ náà àti àwọn etíkun òkun lórí. 2Kí ha kọ́ ni a kọ gbogbo iṣẹ́ agbára àti ipá rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ kíkún nípa títóbi tí ọba fi gbé Mordekai ga, sínú Ìwé Ìtàn àwọn ọba Media àti Persia? 3Mordekai ará Júù, ìgbàkejì Ọba Ahaswerusi, ẹni ńlá láàrin àwọn Júù, ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ ní ìfẹ́ sí, ẹni tí ó ń wá rere fún àwọn ènìyàn rẹ̀, tí ó ń sọ àlàáfíà fún gbogbo irú-ọmọ rẹ̀.